10 Ààlà náà tún yípo lọ sí ìwọ̀ oòrùn Baala, sí apá òkè Seiri, lọ sí apá ìhà àríwá òkè Jearimu (tí a tún ń pè ní Kesaloni), ó bá tún dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sí Beti Ṣemeṣi títí dé ìkọjá Timna.
11 Ó tún gba ti àwọn òkè tí ó wà ní ìhà àríwá Ekironi, ó wá yípo lọ sí Ṣikeroni. Lẹ́yìn náà, ó kọjá lọ sí òkè Baala títí dé Jabineeli, ó wá lọ parí sí Òkun Mẹditarenia.
12 Òkun yìí ni ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn.Òun ni ààlà ilẹ̀ àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
13 Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Joṣua, ó fún Kalebu ọmọ Jefune ní Heburoni gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀ ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda. Orúkọ Heburoni tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Ariba, (tí a tún ń pè ní ìlú Ariba), Ariba yìí ni baba Anaki.
14 Kalebu lé àwọn ìran Anaki mẹtẹẹta jáde níbẹ̀, àwọn ni ìran Ṣeṣai, ìran Ahimani, ati ìran Talimai.
15 Láti ibẹ̀ ó lọ gbógun ti àwọn ará ìlú Debiri. Orúkọ Debiri tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Seferi.
16 Kalebu ṣe ìlérí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹgun Kiriati Seferi tí ó sì gba ìlú náà ni òun yóo fún ní Akisa ọmọ òun, láti fi ṣe aya.