Joṣua 17:10-16 BM

10 Ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìhà gúsù jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu, èyí tí ó wà ní apá ìhà àríwá jẹ́ ti àwọn ọmọ Manase. Òkun Mẹditarenia ni ààlà wọn ní apá ìwọ̀ oòrùn. Ní apá ìhà àríwá, ilẹ̀ wọn lọ títí kan ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, ó sì kan ti ẹ̀yà Isakari ní apá ìlà oòrùn.

11 Ní ilẹ̀ Isakari, ati ti Aṣeri, àwọn ọmọ Manase ni wọ́n ni ìlú Beti Ṣeani ati àwọn ìletò tí wọ́n wà ní agbègbè rẹ̀, Ibileamu ati àwọn ìletò tí wọ́n wà ní agbègbè rẹ̀, ati Dori, Endori, Taanaki ati Megido ati gbogbo àwọn ìletò tí wọ́n wà ní agbègbè wọn. Àwọn náà ni wọ́n ni Nafati.

12 Ṣugbọn àwọn ọmọ Manase kò lè gba àwọn ìlú náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ilẹ̀ náà.

13 Ṣugbọn nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi tipátipá mú àwọn ará Kenaani sìn, wọn kò sì lé wọn jáde patapata.

14 Àwọn ẹ̀yà Josẹfu lọ bá Joṣua, wọ́n wí fún un pé, “Kí ló dé tí o fi fún wa ní ẹyọ ilẹ̀ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwa, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn eniyan wa pọ̀ gan-an, nítorí pé OLUWA ti bukun wa?”

15 Joṣua dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ bá pọ̀, ẹ lọ sí inú igbó, kí ẹ sì gba ilẹ̀ níbẹ̀ ninu ilẹ̀ àwọn ará Perisi ati ti àwọn Refaimu, bí ilẹ̀ olókè ti Efuraimu kò bá tóbi tó fun yín.”

16 Àwọn ẹ̀yà Josẹfu bá dáhùn pé, “Ilẹ̀ olókè yìí kò tó fún wa, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Kenaani tí ń gbé pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn tí wọn ń gbé Beti Ṣani, ati àwọn ìletò tí ó wà ní agbègbè rẹ̀, ati àwọn tí ń gbé àfonífojì Jesireeli.”