Joṣua 17:3-9 BM

3 Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, kò ní ọmọkunrin rárá, àfi kìkì ọmọbinrin. Orúkọ wọn ni Mahila, Noa, Hogila, Milika, ati Tirisa.

4 Wọ́n tọ Eleasari, alufaa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati àwọn àgbààgbà lọ, wọ́n wí fún wọn pé, “OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí ó pín ilẹ̀ fún àwa náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti pín fún àwọn ìbátan wa, tí wọ́n jẹ́ ọkunrin.” Nítorí náà bí OLUWA ti pa á láṣẹ, wọ́n pín ilẹ̀ fún àwọn náà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pín fún àwọn ìbátan wọn tí wọ́n jẹ́ ọkunrin.

5 Ìdí nìyí tí ìpín mẹ́wàá fi kan Manase láìka Gileadi, ati Baṣani ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani.

6 Nítorí pé àwọn ọmọbinrin Manase gba ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìbátan wọn tí wọ́n jẹ́ ọkunrin. Wọ́n pín ilẹ̀ Gileadi fún àwọn ọmọ Manase yòókù.

7 Ilẹ̀ ti Manase bẹ̀rẹ̀ láti Aṣeri títí dé Mikimetati tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Ṣekemu, ààlà rẹ̀ tún lọ sí apá ìhà gúsù ní apá ọ̀dọ̀ àwọn tí wọn ń gbé Entapua.

8 Àwọn ọmọ Manase ni wọ́n ni ilẹ̀ Tapua, ṣugbọn ìlú Tapua gan-an, tí ó wà ní ààlà ilẹ̀ àwọn ọmọ Manase, jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu.

9 Ààlà ilẹ̀ wọn tún lọ sí apá ìsàlẹ̀ títí dé odò Kana, àwọn ìlú wọnyi tí wọ́n wà ní apá gúsù odò náà, láàrin ìlú àwọn ọmọ Manase, jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu. Ààlà àwọn ọmọ Manase tún lọ sí apá àríwá odò náà, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia.