Joṣua 22:25-31 BM

25 Nítorí OLUWA ti fi odò Jọdani ṣe ààlà láàrin àwa pẹlu yín, ẹ̀yin ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ẹ kò ní ìpín ninu nǹkan OLUWA.’ Àwọn ọmọ yín sì lè mú kí àwọn ọmọ wa má sin OLUWA mọ́.

26 Nítorí náà, ni a ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á tẹ́ pẹpẹ kan,’ kì í ṣe fún ẹbọ sísun tabi ẹbọ mìíràn,

27 ṣugbọn yóo wà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, láàrin àwa pẹlu yín, ati àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn wa, pé àwa náà yóo máa sin OLUWA, a óo sì máa rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú rẹ̀. Kí àwọn ọmọ yín má baà wí fún àwọn ọmọ wa ní ọjọ́ iwájú pé, ‘Ẹ kò ní ìpín ninu nǹkan OLUWA.’

28 Èyí ni a fi ronú pé, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀ sí wa, tabi sí àwọn ọmọ ọmọ wa ní ọjọ́ iwájú, a óo lè wí pé, ẹ wo irú pẹpẹ OLUWA tí àwọn baba ńlá wá tẹ́, kì í ṣe pé wọ́n rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀, tabi ẹbọ mìíràn. Ẹ̀rí ni wọ́n fi ṣe láàrin àwa pẹlu yín.

29 A kò jẹ́ ṣe oríkunkun sí OLUWA tabi kí á kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kí a má sì sìn ín mọ́ kí á wá tẹ́ pẹpẹ mìíràn fún ẹbọ sísun tabi ẹbọ alaafia tabi ẹbọ mìíràn, yàtọ̀ sí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa tí ó wà níwájú àgọ́ rẹ̀.”

30 Nígbà tí Finehasi alufaa, ati àwọn olórí ìjọ eniyan, ati àwọn olórí ìdílé Israẹli tí wọ́n wà pẹlu wọn, gbọ́ ohun tí àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase wí, ọ̀rọ̀ náà dùn mọ́ wọn ninu.

31 Finehasi ọmọ Eleasari, alufaa dá wọn lóhùn, ó ní, “Lónìí a mọ̀ pé OLUWA ń bẹ ní ààrin wa, nítorí pé ẹ kò hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí OLUWA, ẹ sì ti gba eniyan Israẹli lọ́wọ́ ìjìyà OLUWA.”