20 Ibikíbi tí ẹ bá wà, tí ẹ bá ti gbọ́ fèrè, ẹ wá péjọ sọ́dọ̀ wa. Ọlọrun wa yóo jà fún wa.”
21 Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà tí àwọn apá kan sì gbé idà lọ́wọ́ láti àárọ̀ di alẹ́.
22 Mo tún sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Kí olukuluku ati iranṣẹ rẹ̀ sùn ní Jerusalẹmu, kí wọ́n lè máa ṣọ́ ìlú lálẹ́, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ ní ojú ọ̀sán.”
23 Nítorí náà, àtèmi ati àwọn arakunrin mi, ati àwọn iranṣẹ mi, ati àwọn olùṣọ́ tí wọ́n tẹ̀lé mi, a kò bọ́ aṣọ lọ́rùn tọ̀sán-tòru, gbogbo wa ni a di ihamọra wa, tí a sì mú nǹkan ìjà lọ́wọ́.