5 Mò ń kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,mo fi egbin ati àgbọ̀nrín inú igbó búra,pé, ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi, títí yóo fi wù ú láti jí.
6 Kí ló ń jáde bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí,tí ó dàbí òpó èéfín,tí ó kún fún òórùn dídùn òjíá ati turari,pẹlu òórùn dídùn àtíkè àwọn oníṣòwò?
7 Wò ó! Solomoni ni wọ́n ń gbé bọ̀, lórí ìtẹ́ rẹ̀,ọgọta akọni ọkunrin, lára àwọn akọni Israẹli,ni ó yí ìtẹ́ rẹ̀ ká.
8 Gbogbo wọn dira ogun pẹlu idà,akọni sì ni wọ́n lójú ogun.Olukuluku dira pẹlu idà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, nítorí ìdágìrì ọ̀gànjọ́.
9 Igi Lẹbanoni ni Solomoni fi ṣe ìtẹ́ rẹ̀.
10 Ó fi fadaka ṣe àwọn ẹsẹ̀ ìjókòó rẹ̀,ó fi wúrà ṣe ẹ̀yìn rẹ̀,Aṣọ elése-àlùkò tí àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu hun ni ó fi ṣe tìmùtìmù ìjókòó rẹ̀.