Samuẹli Keji 2:10-16 BM

10 Ẹni ogoji ọdún ni nígbà tí wọ́n fi jọba lórí Israẹli, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji.Ṣugbọn ẹ̀yìn Dafidi ni gbogbo ẹ̀yà Juda wà.

11 Ọdún meje ààbọ̀ ni Dafidi fi jọba lórí ẹ̀yà Juda ní ìlú Heburoni.

12 Abineri ọmọ Neri ati àwọn iranṣẹ Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ṣígun láti Mahanaimu, lọ sí ìlú Gibeoni.

13 Joabu, tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Seruaya, ati àwọn iranṣẹ Dafidi yòókù lọ pàdé wọn níbi adágún Gibeoni. Àwọn tí wọ́n tẹ̀lé Joabu jókòó sí ẹ̀gbẹ́ kan adágún náà, àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Abineri náà sì jókòó sí òdìkejì.

14 Abineri bá sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí àwọn bíi mélòó kan ninu àwọn ọmọkunrin láti ẹ̀gbẹ́ kinni keji bọ́ siwaju, kí wọ́n fi ohun ìjà dánrawò níwájú wa.”Joabu sì gbà bẹ́ẹ̀.

15 Àwọn mejila bá jáde láti ẹ̀gbẹ́ kinni keji; àwọn mejila ẹ̀gbẹ́ kan dúró fún ẹ̀yà Bẹnjamini ati Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu, wọ́n sì bá àwọn iranṣẹ Dafidi mejila, tí wọ́n jáde láti inú ẹ̀yà Juda jà.

16 Ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ẹ̀gbẹ́ kinni, dojú kọ ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ẹ̀gbẹ́ keji, wọ́n sì gbá ara wọn lórí mú. Ẹnìkínní ti idà rẹ̀ bọ ẹnìkejì rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́, àwọn mẹrẹẹrinlelogun ṣubú lulẹ̀, wọ́n sì kú. Ìdí nìyí tí wọ́n fi sọ ibẹ̀ ní Helikati-hasurimu. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni “Pápá Idà”; ó wà ní Gibeoni.