5 ó ranṣẹ sí wọn pé, “Kí OLUWA bukun yín nítorí pé ẹ ṣe olóòótọ́ sí Saulu ọba wa, ẹ sì sin òkú rẹ̀.
6 Kí OLUWA fi ìfẹ́ ńlá ati òdodo rẹ̀ hàn fun yín. Èmi náà yóo ṣe yín dáradára, nítorí ohun tí ẹ ṣe yìí.
7 Nítorí náà, ẹ mọ́kàn gírí kí ẹ sì ṣe akin; nítorí pé Saulu, oluwa yín ti kú, àwọn eniyan Juda sì ti fi òróró yàn mí gẹ́gẹ́ bí ọba wọn.”
8 Abineri ọmọ Neri, tíí ṣe balogun àwọn ọmọ ogun Saulu, gbé Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu sá lọ sí Mahanaimu ní òdìkejì odò Jọdani.
9 Níbẹ̀ ni ó ti fi Iṣiboṣẹti jọba lórí gbogbo agbègbè Gileadi, Aṣuri, Jesireeli, Efuraimu, Bẹnjamini, ati lórí gbogbo ilẹ̀ Israẹli.
10 Ẹni ogoji ọdún ni nígbà tí wọ́n fi jọba lórí Israẹli, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji.Ṣugbọn ẹ̀yìn Dafidi ni gbogbo ẹ̀yà Juda wà.
11 Ọdún meje ààbọ̀ ni Dafidi fi jọba lórí ẹ̀yà Juda ní ìlú Heburoni.