5 Wọ́n dáhùn pé, “Saulu fẹ́ pa wá run, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ninu wa wà láàyè níbikíbi, ní ilẹ̀ Israẹli.
6 Nítorí náà, fún wa ní meje ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, kí á lè so wọ́n kọ́ níwájú OLUWA ní Gibea, ní orí òkè OLUWA.”Dafidi dáhùn pé, “N óo kó wọn lé yín lọ́wọ́.”
7 Ṣugbọn nítorí majẹmu tí ó wà láàrin Dafidi ati Jonatani, Dafidi kò fi ọwọ́ kan Mẹfiboṣẹti, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu.
8 Ṣugbọn ó mú Arimoni ati Mẹfiboṣẹti àwọn ọmọkunrin mejeeji tí Risipa, ọmọ Aya, bí fún Saulu; ó sì tún mú àwọn ọmọ marun-un tí Merabu, ọmọbinrin Saulu, bí fún Adirieli ọmọ Basilai ará Mehola.
9 Dafidi kó wọn lé àwọn ará Gibeoni lọ́wọ́, àwọn ará Gibeoni sì so wọ́n kọ́ sórí igi, lórí òkè níwájú OLUWA, àwọn mejeeje sì kú papọ̀. Àkókò tí wọ́n kú yìí jẹ́ àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà baali nígbà tí àkókò ìrúwé fẹ́rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀.
10 Risipa, ọmọbinrin Aya, fi aṣọ ọ̀fọ̀ pa àtíbàbà fún ara rẹ̀ lórí òkúta, níbi tí òkú àwọn tí wọ́n pa wà. Ó wà níbẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí di àkókò tí òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Ní ojúmọmọ, kò jẹ́ kí àwọn ẹyẹ jẹ wọ́n ní ọ̀sán, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú fọwọ́ kàn wọ́n lóru.
11 Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí Risipa, ọmọ Aya, obinrin Saulu ṣe,