35 Saulu bá tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA. Pẹpẹ yìí ni pẹpẹ kinni tí Saulu tẹ́ fún OLUWA.
36 Saulu wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ kọlu àwọn ará Filistia ní òru kí á kó ẹrù wọn, kí á sì pa gbogbo wọn títí ilẹ̀ yóo fi mọ́ láì dá ẹnikẹ́ni sí.”Àwọn eniyan náà dá a lóhùn pé, “Ṣe èyí tí ó bá dára lójú rẹ.”Ṣugbọn alufaa wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọ́kọ́ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun ná.”
37 Saulu bá bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun pé, “Ṣé kí n lọ kọlu àwọn ará Filistia? Ṣé o óo fún Israẹli ní ìṣẹ́gun?” Ṣugbọn Ọlọrun kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà.
38 Saulu bá pe gbogbo olórí àwọn eniyan náà jọ, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí á wádìí ohun tí ó fa ẹ̀ṣẹ̀ òní.
39 Mo fi OLUWA alààyè tí ó fún Israẹli ní ìṣẹ́gun búra pé, pípa ni a óo pa ẹni tí ó bá jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí, kì báà jẹ́ Jonatani ọmọ mi.” Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò dá a lóhùn ninu wọn.
40 Saulu bá wí fún gbogbo Israẹli pé, “Gbogbo yín, ẹ dúró ní apá kan, èmi ati Jonatani, ọmọ mi, yóo dúró ní apá keji.”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ.”
41 Saulu bá ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí o kò fi dá iranṣẹ rẹ lóhùn lónìí? OLUWA Ọlọrun Israẹli, bí ó bá jẹ́ pé èmi tabi Jonatani ni a jẹ̀bi, fi Urimu dáhùn. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé àwọn eniyan rẹ ni wọ́n ṣẹ̀, fi Tumimu dáhùn.” Urimu bá mú Jonatani ati Saulu,