1 Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiṣi, ọmọ Abieli, ọmọ Serori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afaya láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini.
2 Ó ní ọmọkunrin kan tí ń jẹ́ Saulu. Saulu yìí jẹ́ arẹwà ọkunrin. Láti èjìká rẹ̀ sókè ni ó fi ga ju ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli lọ, ó sì lẹ́wà ju ẹnikẹ́ni ninu wọn lọ.
3 Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Kiṣi, baba Saulu sọnù. Kiṣi bá sọ fún Saulu ọmọ rẹ̀ pé, “Mú ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ lẹ́yìn, kí ẹ lọ wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wá.”
4 Wọ́n wá gbogbo agbègbè olókè Efuraimu káàkiri, ati gbogbo agbègbè Ṣaliṣa, ṣugbọn wọn kò rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà. Wọ́n wá gbogbo agbègbè Ṣaalimu, ṣugbọn wọn kò rí wọn níbẹ̀. Lẹ́yìn náà wọ́n wá gbogbo ilẹ̀ Bẹnjamini, sibẹsibẹ wọn kò rí wọn.
5 Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Sufu, Saulu sọ fún iranṣẹ tí ó wà pẹlu rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á pada sílé, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi lè má ronú nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́, kí ó máa páyà nítorí tiwa.”
6 Iranṣẹ náà dá a lóhùn, ó ní, “Dúró ná, eniyan Ọlọrun kan wà ní ilẹ̀ yìí, tí gbogbo eniyan ń bu ọlá fún, nítorí pé gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ níí máa ń ṣẹ. Jẹ́ kí á lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, bóyá ó lè sọ ibi tí a óo ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún wa.”
7 Saulu dá a lóhùn pé, “Bí a bá tọ eniyan Ọlọrun yìí lọ nisinsinyii, kí ni a óo mú lọ́wọ́ lọ fún un? Oúnjẹ tí ó wà ninu àpò wa ti tán, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí nǹkankan lọ́wọ́ wa tí a lè fún un. Àbí kí ni a óo fún un?”
8 Iranṣẹ náà dá Saulu lóhùn, ó ní, “Mo ní idamẹrin owó ṣekeli fadaka kan lọ́wọ́, n óo fún un, yóo sì sọ ibi tí a óo ti rí wọn fún wa.”
9 (Ní àtijọ́, ní ilẹ̀ Israẹli, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Ọlọrun, yóo wí pé, òun ń lọ sí ọ̀dọ̀ aríran; nítorí àwọn tí àwa ń pè ní wolii lónìí, aríran ni wọ́n ń pè wọ́n nígbà náà.)
10 Saulu bá dá a lóhùn pé, “O ṣeun, jẹ́ kí á lọ.” Wọ́n bá lọ sí ìlú tí eniyan Ọlọrun yìí wà.
11 Bí wọ́n ti ń gun òkè lọ láti wọ ìlú, wọ́n pàdé àwọn ọmọbinrin tí wọ́n ń jáde lọ pọn omi. Wọ́n bi àwọn ọmọbinrin náà pé, “Ǹjẹ́ aríran wà ní ìlú?”
12 Àwọn ọmọbinrin náà dá wọn lóhùn pé, “Ó wà ní ìlú. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá nisinsinyii ni. Bí ó ti ń wọ ìlú bọ̀ tààrà nìyí, ẹ yára lọ bá a. Àwọn eniyan ní ẹbọ kan tí wọn óo rú ní orí òkè lónìí.
13 Bí ẹ bá tí ń wọ ìlú ni ẹ óo rí i. Ẹ yára kí ẹ lè bá a, kí ó tó lọ sí orí òkè lọ jẹun; nítorí pé àwọn eniyan kò ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóo fi dé. Òun ni ó gbọdọ̀ súre sí ẹbọ náà, kí àwọn tí wọ́n bá pè tó bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. Ẹ tètè máa lọ, ẹ óo bá a.”
14 Saulu ati iranṣẹ rẹ̀ bá gòkè wọ ìlú lọ. Bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n rí Samuẹli tí ń jáde bọ̀ wá sí ọ̀nà ọ̀dọ̀ wọn, ó ń lọ sí orí òkè tí wọ́n ti ń rúbọ.
15 Ó ku ọ̀la kí Saulu dé ni OLUWA ti sọ fún Samuẹli pé,
16 “Ní ìwòyí ọ̀la, n óo rán ọkunrin kan sí ọ láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. O óo ta òróró sí i lórí láti yàn án ní ọba Israẹli, àwọn eniyan mi. Ọkunrin náà ni yóo gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Filistia, nítorí mo ti rí àwọn eniyan mi tí ń jìyà, mo sì ti gbọ́ igbe wọn.”
17 Nígbà tí Samuẹli fi ojú kan Saulu, OLUWA wí fún un pé, “Ọkunrin tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ọ nìyí. Òun ni yóo jọba lórí àwọn eniyan mi.”
18 Saulu tọ Samuẹli lọ, lẹ́nu ibodè, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́, níbo ni ilé aríran?”
19 Samuẹli dá a lóhùn pé, “Èmi aríran náà nìyí. Ẹ máa lọ sí ibi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ, nítorí ẹ óo bá mi jẹun lónìí. Bí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, n óo jẹ́ kí ẹ lọ, n óo sì sọ gbogbo ohun tí ẹ fẹ́ mọ̀ fun yín.
20 Nípa ti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọ́n sọnù láti ìjẹta, ẹ má da ara yín láàmú, wọ́n ti rí wọn. Ṣugbọn ta ni ẹni náà tí àwọn eniyan Israẹli ń fẹ́ tóbẹ́ẹ̀? Ṣebí ìwọ ati ìdílé baba rẹ ni.”
21 Saulu dá a lóhùn, ó ní, “Inú ẹ̀yà Bẹnjamini tí ó kéré jù ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli ni mo ti wá, ati pé ìdílé baba mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Bẹnjamini. Kí ló dé tí o fi ń bá mi sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?”
22 Samuẹli bá mú Saulu ati iranṣẹ rẹ̀ wọ inú gbọ̀ngàn ńlá lọ, ó fi wọ́n jókòó sí ààyè tí ó ṣe pataki jùlọ níbi tabili oúnjẹ tí wọ́n fi àwọn àlejò bí ọgbọ̀n jókòó sí.
23 Ó sọ fún alásè pé kí ó gbé ẹran tí òun ní kí ó fi sọ́tọ̀ wá.
24 Alásè náà bá gbé ẹsẹ̀ ati itan ẹran náà wá, ó gbé e kalẹ̀ níwájú Saulu. Samuẹli wí fún Saulu pé, “Wò ó, ohun tí a ti pèsè sílẹ̀ dè ọ́ ni wọ́n gbé ka iwájú rẹ yìí. Máa jẹ ẹ́, ìwọ ni a fi pamọ́ dè, pé kí o jẹ ẹ́ ní àkókò yìí pẹlu àwọn tí mo pè.”Saulu ati Samuẹli bá jọ jẹun pọ̀ ní ọjọ́ náà.
25 Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá sinu ìlú láti ibi ìrúbọ náà, wọ́n tẹ́ ibùsùn kan fún Saulu lórí òrùlé, ó sì sùn sibẹ.
26 Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́júmọ́, Samuẹli pe Saulu lórí òrùlé, ó ní, “Dìde kí n sìn ọ́ sọ́nà.” Saulu dìde, òun ati Samuẹli bá jáde sí òpópónà.
27 Nígbà tí wọ́n dé ibi odi ìlú, Samuẹli wí fún Saulu pé, “Sọ fún iranṣẹ rẹ kí ó máa nìṣó níwájú dè wá.” Iranṣẹ náà bá bọ́ siwaju, ó ń lọ. Samuẹli sọ fún Saulu pé, “Dúró díẹ̀ níhìn-ín kí n sọ ohun tí Ọlọrun wí fún ọ.”