Samuẹli Kinni 29 BM

Àwọn Ará Filistia Kọ Dafidi

1 Àwọn ará Filistia kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ sí Afeki, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì pa ibùdó sí etí orísun omi tí ó wà ní àfonífojì Jesireeli.

2 Bí àwọn ọba Filistini ti ń kọjá pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn ní ọgọọgọrun-un ati ẹgbẹẹgbẹrun, Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ tò sẹ́yìn ọba Akiṣi.

3 Àwọn olórí ogun Filistini bèèrè pé, “Kí ni àwọn Heberu wọnyi ń ṣe níbí?”Akiṣi sì dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí Dafidi, iranṣẹ Saulu ọba Israẹli nìyí, ó ti wà lọ́dọ̀ mi láti ìgbà pípẹ́, n kò tíì rí àṣìṣe kan lọ́wọ́ rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.”

4 Àwọn olórí ogun náà bínú sí i gidigidi, wọ́n ní, “Sọ fún un, kí ó pada síbi tí o fún un, kí ó má bá wa lọ sójú ogun, kí ó má baà dojú ìjà kọ wá. Kí ni ìwọ rò pé yóo fẹ́ fi bá oluwa rẹ̀ làjà? Ṣebí nípa pípa àwọn ọmọ ogun wa ni.

5 Àbí nítorí Dafidi yìí kọ́ ni àwọn ọmọbinrin Israẹli ṣe ń jó tí wọ́n sì ń kọrin pé,‘Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀,ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀?’ ”

6 Akiṣi pe Dafidi, ó sọ fún un pé, “Mo fi OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí pé o jẹ́ olóòótọ́ sí mi, inú mi sì dùn sí i pé kí o bá mi lọ sójú ogun yìí, nítorí pé n kò tíì rí ẹ̀bi kan lọ́wọ́ rẹ láti ìgbà tí o ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní. Ṣugbọn àwọn olórí ogun kò gbà pé kí o bá wa lọ.

7 Nítorí náà, jọ̀wọ́ pada ní alaafia, kí o má baà múnú bí wọn.”

8 Dafidi dáhùn pé, “Kí ni mo ṣe? Kí ni ìdí rẹ̀ tí n kò fi ní lè lọ bá àwọn ọ̀tá rẹ jà, nígbà tí o kò rí ẹ̀bi kan lọ́wọ́ mi láti ìgbà tí mo ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?”

9 Akiṣi sì dáhùn pé, “Nítòótọ́ ni, mo mọ̀ pé o jẹ́ ẹni rere bí angẹli OLUWA, ṣugbọn àwọn olórí ogun ti sọ pé, o kò lè bá wa lọ sójú ogun.

10 Nítorí náà, dìde ní òwúrọ̀, ìwọ ati àwọn iranṣẹ oluwa rẹ, tí wọ́n bá ọ wá, kí ẹ sì máa lọ ní kété tí ilẹ̀ bá ti mọ́.”

11 Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bá dìde, wọ́n lọ sí ilẹ̀ Filistini, àwọn ọmọ ogun Filistini sì lọ sí Jesireeli.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31