1 Àwọn ará Filistia bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní orí òkè Giliboa. Ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli kú, àwọn yòókù sì sá. Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ pàápàá sá lójú ogun.
2 Ṣugbọn àwọn ará Filistia lé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n pa Jonatani ati Abinadabu ati Malikiṣua, àwọn ọmọ Saulu.
3 Ogun náà le fún Saulu gidigidi, àwọn tafàtafà ta á ní ọfà, ó sì farapa lọpọlọpọ.
4 Ó sọ fún ọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o pa mí, kí àwọn aláìkọlà wọnyi má baà pa mí, kí wọ́n sì fi mí ṣe ẹlẹ́yà.” Ẹ̀rù ba ọmọkunrin náà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, Saulu fa idà rẹ̀ yọ, ó ṣubú lé e lórí, ó sì kú.
5 Nígbà tí ọmọkunrin náà rí i pé Saulu kú, òun náà fa idà rẹ̀ yọ, ó ṣubú lé e lórí ó sì kú.
6 Bẹ́ẹ̀ ni Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹta, ati ọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣe kú ní ọjọ́ kan náà.
7 Nígbà tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli tí wọn ń gbé òdìkejì àfonífojì Jesireeli ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun Israẹli ti sá lójú ogun, ati pé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú; wọ́n sá kúrò ní ìlú wọn. Àwọn ará Filistia bá lọ tẹ̀dó sibẹ.
8 Ní ọjọ́ keji tí àwọn ará Filistia wá láti bọ́ àwọn nǹkan tí ó wà lára àwọn tí wọ́n kú, wọ́n rí òkú Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹta ní òkè Giliboa.
9 Wọ́n gé orí Saulu, wọ́n sì bọ́ ihamọra rẹ̀, wọ́n ranṣẹ lọ sí gbogbo ilẹ̀ Filistini, pé kí wọ́n kéde ìròyìn ayọ̀ náà fún gbogbo eniyan ati ní gbogbo ilé oriṣa wọn.
10 Wọ́n kó ihamọra Saulu sílé Aṣitarotu, oriṣa wọn, wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ ara odi Beti Ṣani.
11 Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi Gileadi gbọ́ ohun tí àwọn ará Filistia ṣe sí Saulu,
12 àwọn tí wọ́n jẹ́ akọni ninu wọ́n lọ sí Beti Ṣani lóru, wọ́n sì gbé òkú Saulu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lára odi Beti Ṣani, wá sí Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì sin wọ́n sibẹ.
13 Wọ́n sin egungun wọn sí abẹ́ igi tamarisiki, ní Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ meje.