1 Lẹ́yìn náà, Samuẹli wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Mo ti ṣe ohun tí ẹ ní kí n ṣe. Mo ti fi ẹnìkan jọba lórí yín.
2 Nisinsinyii, ọba ni yóo máa ṣe olórí yín. Ní tèmi, mo ti dàgbà, ogbó sì ti dé sí mi. Àwọn ọmọ mi sì ń bẹ lọ́dọ̀ yín. Láti ìgbà èwe mi ni mo ti jẹ́ olórí fun yín títí di àkókò yìí.
3 Èmi nìyí níwájú yín yìí, bí mo bá ti ṣe nǹkankan tí kò tọ́, ẹ fi ẹ̀sùn kàn mí níwájú OLUWA ati ọba, ẹni àmì òróró rẹ̀. Ǹjẹ́ mo gba mààlúù ẹnikẹ́ni ninu yín rí? Àbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Tabi ta ni mo ni lára rí? Ǹjẹ́ mo gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni rí? Bí mo bá ti ṣe èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan wọnyi rí, mo ṣetán láti san ohun tí mo gbà pada.”
4 Àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Rárá o, o kò rẹ́ wa jẹ rí, o kò ni wá lára, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì gba ohunkohun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni rí.”
5 Samuẹli dáhùn pé, “OLUWA ati ọba, ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ gbà pé ọwọ́ mi mọ́ patapata.”Àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, OLUWA ni ẹlẹri wa.”
6 Samuẹli tún sọ fún wọn pé, “OLUWA tí ó yan Mose ati Aaroni, tí ó kó àwọn baba ńlá yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti ni ẹlẹ́rìí.
7 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, n óo sì fi ẹ̀sùn kàn yín níwájú OLUWA n óo ran yín létí gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí OLUWA ṣe láti gba àwọn baba ńlá yín kalẹ̀.
8 Nígbà tí Jakọbu ati ìdílé rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tí àwọn ará Ijipti ń ni wọ́n lára, àwọn baba ńlá yín kígbe pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA sì rán Mose ati Aaroni, wọ́n kó wọn jáde kúrò ní Ijipti. Ó sì mú kí wọ́n máa gbé orí ilẹ̀ yìí.
9 Ṣugbọn wọ́n gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn. Wọ́n jagun, OLUWA sì fi wọ́n lé Sisera, olórí ogun Jabini ọba Hasori lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ati ọba Moabu náà sì ṣẹgun wọn.
10 Lẹ́yìn náà, àwọn baba ńlá yín kígbe pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́. Wọ́n ní, ‘A ti ṣẹ̀, nítorí pé a ti kọ OLUWA sílẹ̀, a sì ń sin oriṣa Baali, ati ti Aṣitarotu. Nisinsinyii, gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, a óo sì máa sìn ọ́.’
11 OLUWA bá rán Jerubaali ati Baraki, ati Jẹfuta ati èmi, Samuẹli, láti gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín káàkiri, ó sì jẹ́ kí ẹ wà ní alaafia.
12 Ṣugbọn nígbà tí ẹ rí i pé Nahaṣi, ọba Amoni fẹ́ gbé ogun tì yín, ẹ kọ OLUWA lọ́ba, ẹ wí fún mi pé, ẹ fẹ́ ọba tí yóo jẹ́ alákòóso yín.
13 “Ọba tí ẹ bèèrè fún náà nìyí, ẹ̀yin ni ẹ bèèrè rẹ̀, OLUWA sì ti fun yín nisinsinyii.
14 Bí ẹ bá bẹ̀rù OLUWA, tí ẹ̀ ń sìn ín, tí ẹ̀ ń gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, tí ẹ̀yin ati ọba tí ń ṣe àkóso yín bá ń tẹ̀lé àwọn ìlànà OLUWA Ọlọrun yín, ohun gbogbo ni yóo máa lọ déédé fun yín.
15 Ṣugbọn bí ẹ kò bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, yóo dojú ìjà kọ ẹ̀yin ati ọba yín.
16 Nítorí náà, ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ wo iṣẹ́ ńlá tí OLUWA yóo ṣe.
17 Àkókò ìkórè ọkà nìyí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? N óo gbadura, OLUWA yóo sì jẹ́ kí ààrá sán, kí òjò sì rọ̀. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹ óo mọ̀ pé bíbèèrè tí ẹ bèèrè fún ọba, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni ẹ dá sí OLUWA.”
18 Samuẹli bá gbadura, ní ọjọ́ náà gan-an, OLUWA sán ààrá, ó sì rọ òjò. Ẹ̀rù OLUWA ati ti Samuẹli sì ba gbogbo àwọn eniyan náà.
19 Wọ́n bá wí fún Samuẹli pé, “Gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ fún wa, kí á má baà kú. Nítorí pé a mọ̀ nisinsinyii pé, yàtọ̀ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti dá tẹ́lẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ tún ni bíbèèrè tí a bèèrè fún ọba tún jẹ́ lọ́rùn wa.”
20 Samuẹli dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ẹ ṣe burú, sibẹsibẹ ẹ má ṣe yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, ṣugbọn ẹ máa sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn yín.
21 Ẹ má tẹ̀lé àwọn oriṣa; ohun asán tí kò lérè, tí kò sì lè gbani ni wọ́n.
22 OLUWA kò ní ta eniyan rẹ̀ nù, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀, nítorí pé ó wù ú láti ṣe yín ní eniyan rẹ̀.
23 Ní tèmi, n kò ní ṣẹ̀, nípa aigbadura sí OLUWA fun yín. N óo sì máa kọ yín ní ohun tí ó dára láti máa ṣe ati ọ̀nà tí ó tọ́ fun yín láti máa rìn.
24 Ẹ máa bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì máa sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn yín. Ẹ ranti àwọn nǹkan ńláńlá tí ó ti ṣe fun yín.
25 Ṣugbọn bí ẹ bá tún ṣe nǹkan burúkú, yóo pa ẹ̀yin ati ọba yín run.”