1 Lẹ́yìn tí àpótí OLUWA ti wà ní ilẹ̀ Filistini fún oṣù meje,
2 àwọn ará ilẹ̀ náà pe àwọn babalóòṣà wọn ati àwọn adáhunṣe wọn jọ, wọ́n bi wọ́n pé, “Báwo ni kí á ti ṣe àpótí OLUWA? Bí a óo bá dá a pada sí ibi tí wọ́n ti gbé e wá, kí ni kí á fi ranṣẹ pẹlu rẹ̀?”
3 Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ óo bá dá àpótí Ọlọrun Israẹli pada, ẹ gbọdọ̀ dá a pada pẹlu ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, àpótí ẹ̀rí náà kò gbọdọ̀ pada lọ lásán, láìsí nǹkan ètùtù. Bẹ́ẹ̀ ni ara yín yóo ṣe yá, ẹ óo sì mọ ìdí tí Ọlọrun fi ń jẹ yín níyà.”
4 Àwọn eniyan náà bi wọ́n pé, “Kí ni kí á fi ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù?”Àwọn babalóòṣà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ fi wúrà yá ère kókó ọlọ́yún marun-un, ati ti èkúté marun-un, kí ẹ fi ranṣẹ. Kókó ọlọ́yún wúrà marun-un ati èkúté marun-un dúró fún àwọn ọba Filistini maraarun. Nítorí àjàkálẹ̀ àrùn kan náà ni ó kọlu gbogbo yín ati àwọn ọba yín maraarun.
5 Ẹ gbọdọ̀ fi wúrà yá ère kókó ọlọ́yún yín ati ti èkúté tí ń ba ilẹ̀ yín jẹ́, kí ẹ sì fi ògo fún Ọlọrun Israẹli bóyá ó lè dáwọ́ ìjìyà rẹ̀ dúró lórí ẹ̀yin ati oriṣa yín, ati ilẹ̀ yín.
6 Kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ ṣe oríkunkun, bí ọba ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ará Ijipti. Ẹ ranti bí Ọlọrun ti fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà títí tí wọ́n fi jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ. Wọ́n kúkú lọ!
7 Nítorí náà ẹ kan kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun kan, kí ẹ sì tọ́jú abo mààlúù meji tí ń fún ọmọ lọ́mú tí ẹnikẹ́ni kò sì so àjàgà mọ́ lọ́rùn rí, ẹ so kẹ̀kẹ́ ẹrù náà mọ́ wọn lọ́rùn, kí ẹ sì lé àwọn ọmọ wọn pada sílé.
8 Ẹ gbé àpótí OLUWA lé orí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà. Ẹ kó àwọn kókó ọlọ́yún ati àwọn èkúté tí ẹ fi wúrà ṣe, tí ẹ fẹ́ fi ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù sinu àpótí kan, kí ẹ wá gbé e sí ẹ̀gbẹ́ àpótí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ẹ ti kẹ̀kẹ́ ẹrù yìí sójú ọ̀nà, kí ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ fúnrarẹ̀.
9 Ẹ máa kíyèsí i bí ó bá ti ń lọ. Bí ó bá doríkọ ọ̀nà ìlú Beti Ṣemeṣi, a jẹ́ pé Ọlọrun àwọn ọmọ Israẹli ni ó kó gbogbo àjálù yìí bá wa. Bí kò bá doríkọ ibẹ̀, a óo mọ̀ pé kì í ṣe òun ló rán àjálù náà sí wa, a jẹ́ pé ó kàn dé bá wa ni.”
10 Àwọn eniyan náà ṣe bí àwọn babalóòṣà ti wí. Wọ́n mú mààlúù meji tí wọn ń fún ọmọ lọ́mú lọ́wọ́, wọ́n so kẹ̀kẹ́ ẹrù náà mọ́ wọn lọ́rùn, wọ́n sì ti àwọn ọmọ wọn mọ́lé.
11 Wọ́n gbé àpótí OLUWA sinu kẹ̀kẹ́ ẹrù náà, pẹlu àpótí tí wọ́n kó àwọn èkúté wúrà ati kókó ọlọ́yún wúrà náà sí.
12 Àwọn mààlúù yìí bá doríkọ ọ̀nà Beti Ṣemeṣi, wọ́n ń lọ tààrà láì yà sọ́tùn-ún tabi sósì. Wọ́n ń ké bí wọ́n ti ń lọ. Àwọn ọba Filistini maraarun tẹ̀lé wọn títí dé odi Beti Ṣemeṣi.
13 Àwọn ará ìlú Beti ṣemeṣi ń kórè ọkà lọ́wọ́ ní àfonífojì náà, bí wọ́n ti gbójú sókè, wọ́n rí àpótí ẹ̀rí. Inú wọn dùn pupọ pupọ bí wọ́n ti rí i.
14 Nígbà tí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà dé ibi oko Joṣua, ará Beti Ṣemeṣi, ó dúró níbẹ̀. Àpáta ńlá kan wà níbẹ̀, àwọn eniyan náà bá gé igi tí wọ́n fi kan kẹ̀kẹ́ ẹrù náà sí wẹ́wẹ́, wọ́n pa mààlúù mejeeji, wọ́n sì fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA.
15 Àwọn ọmọ Lefi bá gbé àpótí OLUWA náà, ati àpótí tí àwọn ohun tí wọ́n fi wúrà ṣe wà, wọ́n gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Lẹ́yìn náà, àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi rú ẹbọ sísun, ati oríṣìíríṣìí ẹbọ mìíràn sí OLUWA ní ọjọ́ náà.
16 Àwọn ọba Filistini ń wò wọ́n bí wọ́n ti ń ṣe, lẹ́yìn náà, wọ́n yipada sí ìlú Ekironi ní ọjọ́ náà gan-an.
17 Àwọn ará Filistia fi kókó ọlọ́yún marun-un náà tí wọ́n fi wúrà ṣe ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù. Ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ìlú kọ̀ọ̀kan; Aṣidodu, Gasa, Aṣikeloni, Gati ati Ekironi.
18 Wọ́n sì fi àwọn èkúté marun-un tí wọ́n fi wúrà ṣe ranṣẹ. Èkúté kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ìlú àwọn ọba Filistini maraarun. Àwọn maraarun wà fún àwọn ìlú olódi àwọn ọba Filistini, pẹlu àwọn ìletò kéékèèké wọn, tí kò ní odi. Àpáta ńlá tí ó wà ninu oko Joṣua ará Beti Ṣemeṣi, tí àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí OLUWA náà lé wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ títí di òní olónìí.
19 Aadọrin ninu àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ni OLUWA pa, nítorí pé, wọ́n yọjú wo inú àpótí OLUWA náà. Àwọn eniyan náà sì ṣọ̀fọ̀ nítorí pé OLUWA pa ọpọlọpọ ninu wọn.
20 Àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ní, “Ta ló lè dúró níwájú OLUWA Ọlọrun mímọ́ yìí? Ọ̀dọ̀ ta ni yóo fẹ́ lọ, tí yóo fi kúrò lọ́dọ̀ wa?”
21 Wọ́n bá ranṣẹ sí àwọn ará ìlú Kiriati Jearimu pé, “Àwọn ará Filistia ti dá àpótí OLUWA pada. Ẹ wá gbé e.”