Samuẹli Kinni 17 BM

Goliati Pe Àwọn Ọmọ Israẹli Níjà

1 Àwọn ọmọ ogun Filistini kó ara wọn jọ sí Soko, ìlú kan ní ilẹ̀ Juda láti bá Israẹli jagun. Wọ́n pa ibùdó wọn sí Efesi Damimu, tí ó wà láàrin Soko ati Aseka.

2 Saulu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli pa ibùdó tiwọn sí àfonífojì Ela, wọ́n sì múra ogun de àwọn ọmọ ogun Filistini.

3 Àwọn Filistini dúró lórí òkè ní apá kan, àwọn Israẹli sì dúró lórí òkè ní apá keji. Àfonífojì kan sì wà láàrin wọn.

4 Akikanju ọkunrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Goliati, ará ìlú Gati, jáde wá láti ààrin àwọn Filistini. Ó ga ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹfa ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.

5 Ó dé àṣíborí bàbà, ó wọ ẹ̀wù tí wọ́n fi bàbà pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) ṣekeli.

6 Ó ní ihamọra bàbà ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì gbé ọ̀kọ̀ bàbà kan sí èjìká rẹ̀.

7 Ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì dàbí igi òfì, irin tí ó wà lórí ọ̀kọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹta (600) òṣùnwọ̀n ṣekeli. Ẹni tí ń ru asà rẹ̀ sì ń rìn níwájú rẹ̀.

8 Goliati dúró, ó sì kígbe pe àwọn ọmọ Israẹli, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó ara yín jọ láti jagun? Ṣebí Filistini kan ni èmi, ẹ̀yin náà sì jẹ́ ẹrú Saulu? Ẹ̀yin ẹ yan ọkunrin kan láàrin yín tí yóo sọ̀kalẹ̀ wá bá mi jà.

9 Bí ó bá pa mí, a óo di ẹrú yín. Ṣugbọn bí mo bá ṣẹgun rẹ̀, tí mo sì pa á, ẹ óo di ẹrú wa.

10 Mo pe ẹ̀yin ọmọ ogun Israẹli níjà lónìí, ẹ yan ọkunrin kan, kí ó wá bá mi jà.”

11 Nígbà tí Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbọ́, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.

Dafidi ní Ibùdó Saulu

12 Ọmọ Jese ni Dafidi, ará Efurati ní Bẹtilẹhẹmu ti Juda; Ọmọkunrin mẹjọ ni Jese bí, ó sì ti di arúgbó nígbà tí Saulu jọba.

13 Àwọn mẹta tí wọ́n dàgbà jùlọ láàrin àwọn ọmọ Jese bá Saulu lọ sójú ogun. Eliabu ni orúkọ àkọ́bí. Abinadabu ni ti ekeji, Ṣama sì ni ti ẹkẹta.

14 Dafidi ni àbíkẹ́yìn patapata; àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹta náà sì wà ninu àwọn ọmọ ogun Saulu.

15 Dafidi a máa lọ sí Bẹtilẹhẹmu nígbà gbogbo láti tọ́jú agbo ẹran baba rẹ̀.

16 Odidi ogoji ọjọ́ ni Goliati fi pe àwọn ọmọ ogun Israẹli níjà ní àràárọ̀ ati ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́.

17 Ní ọjọ́ kan, Jese sọ fún Dafidi pé, “Jọ̀wọ́, mú ìwọ̀n efa àgbàdo yíyan kan, ati burẹdi mẹ́wàá yìí lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ní ibùdó ogun.

18 Mú wàrà sísè mẹ́wàá yìí lọ́wọ́ fún olórí ogun ikọ̀ wọn, kí o sì bá mi wo alaafia àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ, kí o gba nǹkankan bọ̀ lọ́dọ̀ wọn tí yóo fihàn mí pé alaafia ni wọ́n wà.”

19 Saulu ọba, ati àwọn ẹ̀gbọ́n Dafidi ati àwọn ọmọ ogun yòókù wà ní àfonífojì Ela níbi tí wọ́n ti ń bá àwọn Filistini jà.

20 Dafidi dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó fi ẹnìkan ṣọ́ agbo ẹran rẹ̀, ó mú oúnjẹ náà, ó sì lọ gẹ́gẹ́ bí Jese ti pàṣẹ fún un. Ó dé ibùdó ogun ní àkókò tí àwọn ọmọ ogun ń lọ sójú ogun, wọ́n ń hó ìhó ogun.

21 Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Filistini dúró ní ipò wọn, wọ́n ń wo ara wọn.

22 Dafidi fún olùtọ́jú ẹrù àwọn ọmọ ogun ní oúnjẹ tí ó gbé lọ, ó sì sáré tọ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ sójú ogun láti kí wọn.

23 Bí ó ti ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Goliati wá láti pe àwọn ọmọ ogun Israẹli níjà. Ó sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń sọ ọ́; Dafidi sì gbọ́.

24 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Israẹli rí Goliati, ẹ̀rù bà wọ́n; wọ́n sì sá lọ.

25 Wọ́n ní, “Ẹ wo ọkunrin yìí, ẹ gbọ́ bí ó ti ń pe Israẹli níjà? Ọba sì ti sọ pé ẹni tí ó bá lè pa á yóo gba ẹ̀bùn lọpọlọpọ. Òun yóo sì fi ọmọbinrin òun fún olúwarẹ̀, ilé baba rẹ̀ yóo sì di òmìnira ní ilẹ̀ Israẹli: kò ní san owó orí mọ́.”

26 Dafidi bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọkunrin náà pé, “Kí ni ọba ṣe ìlérí pé òun ó fún ẹni tí ó bá pa Filistini yìí, tí ó sì mú ẹ̀gàn kúrò lára Israẹli? Ta ni aláìkọlà Filistini yìí tí ń pẹ̀gàn àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè?”

27 Àwọn ọkunrin náà sì sọ ohun tí ọba sọ pé òun yóo ṣe fún ẹni tí ó bá pa ọkunrin náà fún Dafidi.

28 Nígbà tí Eliabu, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àgbà gbọ́ tí ó ń bá àwọn ọkunrin náà sọ̀rọ̀, ó bínú sí Dafidi, ó ní, “Kí ni ìwọ ń wá níbí? Ta ni ó ń tọ́jú àwọn aguntan rẹ ninu pápá? Ìwọ onigbeeraga ati ọlọ́kàn líle yìí, nítorí kí o lè wo ogun ni o ṣe wá síbí.”

29 Dafidi sì dáhùn pé, “Kí ni mo ṣe nisinsinyii? Ṣebí ọ̀rọ̀ lásán ni mò ń sọ.”

30 Dafidi yipada kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn, ó tún bèèrè ìbéèrè kan náà. Àwọn ọkunrin náà sì fún un ní èsì bíi ti iṣaaju.

31 Àwọn ọmọ ogun náà sọ ọ̀rọ̀ tí Dafidi sọ níwájú Saulu, Saulu bá ranṣẹ pè é.

32 Dafidi sọ fún Saulu pé, “Ẹ má bẹ̀rù ọkunrin yìí; èmi, iranṣẹ rẹ óo lọ bá a jà.”

33 Saulu bá sọ fún Dafidi pé, “O kò lè bá Filistini yìí jà, nítorí pé ọmọde ni ọ́, òun sì ti jẹ́ jagunjagun láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.”

34 Dafidi dáhùn pé, “Ìgbàkúùgbà tí èmi iranṣẹ rẹ bá ń ṣọ́ agbo aguntan baba mi, tí kinniun tabi ẹranko beari bá gbé ọ̀kan ninu aguntan náà,

35 n óo tẹ̀lé e lọ, n óo lù ú, n óo sì gba aguntan náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Bí ó bá sì kọjú ìjà sí mi, n óo di ọ̀fun rẹ̀ mú, n óo sì pa á.

36 Èmi iranṣẹ rẹ yìí ti pa àwọn kinniun ati àwọn ẹranko beari rí, aláìkọlà Filistini yìí yóo sì dàbí ọ̀kan ninu wọn, nítorí pé, ó ti pe àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè níjà.

37 OLUWA tí ó gbà mí lọ́wọ́ kinniun ati beari yóo gbà mí lọ́wọ́ Filistini yìí.”Saulu bá sọ fún Dafidi pé, “Máa lọ, OLUWA yóo wà pẹlu rẹ.”

38 Saulu gbé ihamọra ogun rẹ̀ wọ Dafidi, ó fi àṣíborí idẹ kan dé e lórí, ó sì gbé ẹ̀wù tí a fi irin pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe wọ̀ ọ́.

39 Dafidi di idà Saulu mọ́ ihamọra náà, ó sì gbìyànjú láti rìn, ṣugbọn kò lè rìn nítorí pé kò wọ ihamọra ogun rí. Dafidi sọ fún Saulu pé, “N kò lè lo ihamọra yìí, nítorí pé n kò wọ̀ ọ́ rí.” Dafidi bá tú wọn kúrò lára rẹ̀.

40 Ó mú ọ̀pá darandaran rẹ̀, ó ṣa òkúta marun-un tí ń dán ninu odò, ó kó wọn sinu àpò rẹ̀, ó mú kànnàkànnà rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì lọ bá Filistini náà.

Dafidi Ṣẹgun Goliati

41 Filistini náà sì ń rìn bọ̀ wá pàdé Dafidi; ẹni tí ń ru asà rẹ̀ sì wà níwájú rẹ̀.

42 Nígbà tí ó rí Dafidi dáradára, ó wò ó pé ọmọ kékeré kan lásán, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́wà ni, nítorí náà, ó fojú tẹmbẹlu rẹ̀.

43 Ó bi Dafidi pé, “Ṣé ajá ni mí ni, tí o fi ń mú ọ̀pá tọ̀ mí bọ̀?” Ó fi Dafidi bú ní orúkọ oriṣa rẹ̀,

44 ó sì wí pé, “Sún mọ́ mi níhìn-ín, n óo sì fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ati ẹranko jẹ.”

45 Dafidi dáhùn pé, “Ìwọ ń bọ̀ wá bá mi jà pẹlu idà ati ọ̀kọ̀, ṣugbọn èmi ń bọ̀ wá pàdé rẹ ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun Israẹli, tí ò ń pẹ̀gàn.

46 Lónìí yìí ni OLUWA yóo fà ọ́ lé mi lọ́wọ́, n óo pa ọ́, n óo gé orí rẹ, n óo sì fi òkú àwọn ọmọ ogun Filistini fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ati ẹranko ìgbẹ́. Gbogbo ayé yóo sì mọ̀ pé Ọlọrun wà fún Israẹli.

47 Gbogbo àwọn eniyan wọnyi yóo sì mọ̀ dájú pé OLUWA kò nílò idà ati ọ̀kọ̀ láti gba eniyan là. Ti OLUWA ni ogun yìí, yóo sì gbé mi borí rẹ̀.”

48 Bí Filistini náà ṣe ń bọ̀ láti pàdé Dafidi, Dafidi sáré sí ààlà ogun láti pàdé rẹ̀.

49 Dafidi mú òkúta kan jáde láti inú àpò rẹ̀, ó fi kànnàkànnà rẹ̀ ta òkúta náà, òkúta náà wọ agbárí Goliati lọ, ó sì ṣubú lulẹ̀.

50 Dafidi ṣẹgun Filistini náà láìní idà lọ́wọ́; kànnàkànnà ati òkúta ni ó fi pa á.

51 Dafidi sáré sí Goliati, ó yọ idà Goliati kúrò ninu àkọ̀, ó sì fi gé orí rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Filistini rí i pé akikanju àwọn ti kú, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ.

52 Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Juda hó ìhó ogun, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn Filistini lọ. Wọ́n lé wọn títí dé Gati ati dé ẹnu ibodè Ekironi. Àwọn Filistini tí wọ́n fara gbọgbẹ́ sì ṣubú láti Ṣaaraimu títí dé Gati ati Ekironi.

53 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Israẹli pada dé, wọ́n lọ kó ìkógun ninu ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini.

54 Dafidi gbé orí ati ihamọra Goliati; ó gbé orí rẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu, ṣugbọn ó kó ihamọra rẹ̀ sinu àgọ́ tirẹ̀.

Dafidi níwájú Saulu

55 Nígbà tí Saulu rí Dafidi tí ó ń lọ bá Goliati jà, ó bèèrè lọ́wọ́ Abineri, olórí ogun rẹ̀ pé, “Ọmọ ta ni ọmọkunrin yìí?”Abineri dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, n kò mọ̀.”

56 Ọba pàṣẹ fún un pé kí ó wádìí ọmọ ẹni tí ọmọ náà í ṣe.

57 Nígbà tí Dafidi pada sí ibùdó lẹ́yìn tí ó ti pa Goliati, Abineri mú un lọ siwaju Saulu, pẹlu orí Goliati ní ọwọ́ rẹ̀.

58 Saulu bi í léèrè pé, “Ọmọ, ta ni baba rẹ?”Dafidi dáhùn pé, “Ọmọ Jese ni mí, iranṣẹ rẹ, tí ń gbé Bẹtilẹhẹmu.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31