1 Dafidi rò ní ọkàn rẹ̀ pé Saulu yóo pa òun ní ọjọ́ kan, nítorí náà ohun tí ó dára jù ni kí òun sá àsálà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ó ní Saulu yóo dẹ́kun láti máa wá òun kiri ní ilẹ̀ Israẹli, òun óo sì fi bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
2 Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹta (600), bá lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati.
3 Wọ́n ń gbé Gati pẹlu àwọn ará ilé wọn. Àwọn aya Dafidi mejeeji, Ahinoamu ará Jesireeli ati Abigaili ará Kamẹli, opó Nabali, sì wà pẹlu rẹ̀ níbẹ̀.
4 Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi ti sá àsálà lọ sí Gati, ó dẹ́kun láti máa wá a kiri.
5 Dafidi sì sọ fún Akiṣi pé, “Bí mo bá rí ojurere rẹ, jọ̀wọ́ fún mi ní ààyè ní ọ̀kan ninu àwọn ìletò agbègbè yìí kí n máa gbé. Kí ló dé tí èmi iranṣẹ rẹ yóo máa gbé inú ìlú kan náà pẹlu rẹ?”
6 Akiṣi fún un ní ìlú Sikilagi, nítorí náà ni Sikilagi fi jẹ́ ti àwọn ọba Juda títí di òní yìí.
7 Dafidi gbé ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ọdún kan ati oṣù mẹrin.
8 Ní àkókò náà, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti àwọn ará Geṣuri, ati àwọn ará Girisi ati àwọn Amaleki, tí wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ fún ìgbà pípẹ́, títí dé Ṣuri ati ilẹ̀ Ijipti.
9 Dafidi pa gbogbo wọn, lọkunrin ati lobinrin, ó sì kó àwọn aguntan, mààlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ràkúnmí wọn, ati aṣọ wọn, ó sì pada lọ bá Akiṣi.
10 Bí Akiṣi bá bèèrè pé, “Àwọn wo ni ẹ kógun lọ bá lónìí?” Dafidi á sì dáhùn pé, “Ìhà gúsù Juda ni, tabi kí ó sọ wí pé ìhà gúsù Jerameeli tabi ìhà gúsù Keni.”
11 Dafidi kò dá ẹnìkankan sí yálà ọkunrin tabi obinrin kí wọ́n má baà mú ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lọ sí Gati, bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ń ṣe ní gbogbo ìgbà tí ó ń gbé ààrin àwọn ará Filistia.
12 Ṣugbọn Akiṣi gba Dafidi gbọ́, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀, kórìíra rẹ̀ lọpọlọpọ, nítorí náà yóo jẹ́ iranṣẹ mi laelae.”