1 Nígbà tí ó ṣe, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Akiṣi sọ fún Dafidi pé, “Ìwọ ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ yóo jà fún mi.”
2 Dafidi dáhùn pé, “Ó dára, o óo sì rí ohun tí èmi iranṣẹ rẹ lè ṣe.”Akiṣi bá ní, òun óo fi Dafidi ṣe olùṣọ́ òun títí lae.
3 Samuẹli ti kú, àwọn Israẹli ti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti sin ín sí Rama ìlú rẹ̀. Saulu ti lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní ilẹ̀ Israẹli.
4 Àwọn ará Filistia sì kó ara wọn jọ, wọ́n pa ibùdó sí Ṣunemu. Saulu náà kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, wọ́n pa ibùdó sí Giliboa.
5 Nígbà tí Saulu rí àwọn ọmọ ogun Filistini, àyà rẹ̀ já, ẹ̀rù sì bà á lọpọlọpọ.
6 Nígbà tí Saulu bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ohun tí yóo ṣe, OLUWA kò dá a lóhùn yálà nípa àlá tabi nípa Urimu tabi nípasẹ̀ àwọn wolii.
7 Saulu bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obinrin kan tí ó bá jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀, kí n lè lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ rẹ̀.”Wọn sì sọ fún un pé, “Obinrin kan wà ní Endori tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀.”
8 Saulu pa ara dà, ó wọ aṣọ mìíràn, òun pẹlu àwọn ọkunrin meji kan lọ sọ́dọ̀ obinrin náà ní òru, Saulu sì sọ fún obinrin náà pé, “Lo ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ rẹ láti pe ẹni tí mo bá sọ fún ọ wá.”
9 Obinrin náà dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń dẹ tàkúté fún mi láti pa mí? O ṣá mọ ohun tí Saulu ọba ṣe, tí ó lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní Israẹli.”
10 Saulu bá búra ní orúkọ OLUWA pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, ibi kan kò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ nítorí èyí.”
11 Obinrin náà dáhùn pé, “Ta ni kí n pè fún ọ?”Saulu dáhùn pe, “Pe Samuẹli fún mi.”
12 Nígbà tí obinrin náà rí Samuẹli, ó kígbe lóhùn rara pé, “Kí ló dé tí o fi tàn mí? Àṣé Saulu ọba ni ọ́.”
13 Saulu bá sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, sọ ohun tí o rí fún mi.”Obinrin náà dáhùn pé, “Mo rí ẹbọra kan, tí ń jáde bọ̀ láti inú ilẹ̀.”
14 Saulu bèèrè pé, “Báwo ló rí?”Obinrin náà dáhùn pé, “Ọkunrin arúgbó kan ló ń bọ̀, ó sì fi aṣọ bora.”Saulu mọ̀ pé Samuẹli ni, ó sì tẹríba.
15 Samuẹli bi Saulu pé, “Kí ló dé tí o fi ń yọ mí lẹ́nu? Kí ló dé tí o fi gbé mi dìde?”Saulu dáhùn pé, “Mo wà ninu ìpọ́njú ńlá nítorí pé àwọn ará Filistia ń bá mi jagun, Ọlọrun sì ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí pé kò fún mi ní ìtọ́sọ́nà, yálà láti ẹnu wolii kan ni, tabi lójú àlá. Nítorí náà ni mo ṣe pè ọ́, pé kí o lè sọ ohun tí n óo ṣe fún mi.”
16 Samuẹli dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń bi mí, nígbà tí OLUWA ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ó sì ti di ọ̀tá rẹ?
17 OLUWA ti ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí ó sọ láti ẹnu mi. Ó ti gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ, ó sì ti fún Dafidi, aládùúgbò rẹ.
18 O ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, nítorí pé, o kò pa gbogbo àwọn ará Amaleki ati àwọn nǹkan ìní wọn run. Ìdí nìyí tí OLUWA fi ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ọ lónìí.
19 OLUWA yóo fa ìwọ ati Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Ní ọ̀la ni ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ yóo kú; OLUWA yóo sì fa àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́.”
20 Lẹ́sẹ̀kan náà, Saulu ṣubú lulẹ̀ gbalaja, nítorí pé ohun ti Samuẹli sọ dẹ́rùbà á gidigidi, àárẹ̀ sì mú un nítorí pé, kò jẹun ní gbogbo ọ̀sán ati òru náà.
21 Nígbà tí obinrin náà rí i pé ó wà ninu ọpọlọpọ ìbànújẹ́, ó sọ fún un pé, “Oluwa mi, mo fi ẹ̀mí mi wéwu láti ṣe ohun tí o bèèrè.
22 Ǹjẹ́, nisinsinyii, jọ̀wọ́ ṣe ohun tí mò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ fún mi. Jẹ́ kí n tọ́jú oúnjẹ fún ọ, kí o jẹ ẹ́, kí o lè lókun nígbà tí o bá ń lọ.”
23 Saulu kọ̀, kò fẹ́ jẹun. Ṣugbon àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati obinrin náà bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹun. Ó gbà, ó dìde nílẹ̀, ó sì jókòó lórí ibùsùn.
24 Obinrin náà yára pa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí ó ń sìn, ó sì ṣe burẹdi díẹ̀ láì fi ìwúkàrà sí i.
25 Ó gbé e kalẹ̀ níwájú wọn; Saulu ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ jẹ ẹ́, wọ́n sì jáde lọ ní òru náà.