43 Saulu bèèrè lọ́wọ́ Jonatani pé kí ó sọ ohun tí ó ṣe fún òun.Jonatani dá a lóhùn pé, “Mo ti ọ̀pá tí mo mú lọ́wọ́ bọ inú oyin, mo sì lá a. Èmi nìyí, mo ṣetán láti kú.”
44 Saulu dá a lóhùn pé, “Láì sí àní àní, pípa ni wọn yóo pa ọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí Ọlọrun lù mí pa.”
45 Nígbà náà ni àwọn eniyan wí fún Saulu pé, “Ṣé a óo pa Jonatani ni, ẹni tí ó ti ṣẹ́ ogun ńlá fún Israẹli? Kí á má rí i. Bí OLUWA tí ń bẹ láàyè, ẹyọ irun orí rẹ̀ kan kò ní bọ́ sílẹ̀. Agbára Ọlọrun ni ó fi ṣe ohun tí ó ṣe lónìí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan náà ṣe gba Jonatani kalẹ̀, tí wọn kò sì jẹ́ kí wọ́n pa á.
46 Lẹ́yìn èyí, Saulu kò lépa àwọn ará Filistia mọ́. Àwọn Filistini sì pada lọ sí agbègbè wọn.
47 Lẹ́yìn tí Saulu ti di ọba Israẹli tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọ̀tá tí wọ́n yí i ká jagun; àwọn bíi: Moabu, Amoni, ati Edomu, ọba ilẹ̀ Soba, ati ti ilẹ̀ Filistini. Ní gbogbo ibi tí ó ti jagun ni ó ti pa wọ́n ní ìpakúpa.
48 Ó jagun gẹ́gẹ́ bí akikanju, ó ṣẹgun àwọn ará Amaleki. Ó sì gba Israẹli kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fi ogun kó wọn.
49 Àwọn ọmọ Saulu lọkunrin ni Jonatani, Iṣifi, ati Malikiṣua. Orúkọ ọmọbinrin rẹ̀ àgbà ni Merabu, ti èyí àbúrò ni Mikali.