6 Bí wọ́n ti ń pada bọ̀ wálé, lẹ́yìn tí Dafidi ti pa Goliati, àwọn obinrin jáde láti gbogbo ìlú Israẹli, wọ́n lọ pàdé Saulu ọba, pẹlu orin ati ijó, wọ́n ń lu aro, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀ pẹlu àwọn ohun èlò orin.
7 Bí wọ́n ti ń jó, wọ́n ń kọrin báyìí pé,“Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀,ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀.”
8 Inú Saulu kò dùn sí orin tí wọ́n ń kọ, inú sì bí i gidigidi. Ó ní, “Wọ́n fún Dafidi ní ẹgbẹẹgbaarun ṣugbọn wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹrun, kí ló kù tí wọn óo fún un ju ìjọba mi lọ.”
9 Láti ọjọ́ náà ni Saulu ti ń ṣe ìlara Dafidi.
10 Ní ọjọ́ keji, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bà lé Saulu, ó sì ń sọ kántankàntan láàrin ilé rẹ̀. Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí ta hapu fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ọ̀kọ̀ kan wà lọ́wọ́ Saulu.
11 Ó ju ọ̀kọ̀ náà, ó ní kí òun fi gún Dafidi ní àgúnmọ́ ògiri. Ó ju ọ̀kọ̀ náà nígbà meji, ṣugbọn Dafidi yẹ̀ ẹ́ lẹẹmejeeji.
12 Saulu bẹ̀rù Dafidi nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ṣugbọn OLUWA kọ òun sílẹ̀.