1 Nígbà tí Samuẹli kú, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kó ara wọn jọ láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì sin òkú rẹ̀ sí ilé rẹ̀ ní Rama.Lẹ́yìn náà, Dafidi lọ sí aṣálẹ̀ Parani.
2 Ọkunrin kan wà ní ìlú Maoni tí ń ṣe òwò ní Kamẹli. Ọkunrin náà ní ọrọ̀ lọpọlọpọ; ó ní ẹgbẹẹdogun aguntan (3,000) ati ẹgbẹrun (1,000) ewúrẹ́, Kamẹli níí ti máa ń gé irun aguntan rẹ̀.
3 Orúkọ ọkunrin náà ni Nabali, iyawo rẹ̀ sì ń jẹ́ Abigaili. Obinrin náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n ati arẹwà, ṣugbọn ọkọ rẹ̀ jẹ́ òǹrorò ati eniyan burúkú. Ìdílé Kalebu ni ìdílé rẹ̀.
4 Dafidi gbọ́ ninu aṣálẹ̀ pé Nabali ń gé irun aguntan rẹ̀,
5 ó bá rán ọdọmọkunrin mẹ́wàá lọ sí Kamẹli láti lọ rí Nabali, kí wọ́n sì kí i ní orúkọ òun.
6 Ó ní kí wọ́n kí i báyìí pé, “Alaafia fún ọ, ati fún ilé rẹ ati fún gbogbo ohun tí o ní.