1 Ní gbogbo àkókò tí Samuẹli wà ní ọmọde, tí ó ń ṣiṣẹ́ fún OLUWA lábẹ́ Eli, OLUWA kò fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ mọ́, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí ìran rírí láti ọ̀dọ̀ OLUWA mọ́.
2 Ní àkókò yìí, ojú Eli ti di bàìbàì, kò ríran dáradára mọ́. Òun sùn sinu yàrá tirẹ̀,
3 ṣugbọn Samuẹli sùn ninu ilé OLUWA, níbi tí àpótí Ọlọrun wà. Iná fìtílà ibi mímọ́ kò tíì jó tán.
4 OLUWA bá pe Samuẹli, ó ní, “Samuẹli! Samuẹli!” Samuẹli dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
5 Ó bá dìde, ó sáré tọ Eli lọ, ó ní, “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.”Ṣugbọn Eli dá a lóhùn pé, “N kò pè ọ́, pada lọ sùn.” Samuẹli bá pada lọ sùn.
6 OLUWA tún pe Samuẹli. Samuẹli dìde, ó tún tọ Eli lọ, ó ní, “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.” Eli tún dá a lóhùn pé, “N kò pè ọ́, ọmọ mi, pada lọ sùn.”
7 Samuẹli kò mọ̀ pé OLUWA ni, nítorí OLUWA kò tíì bá a sọ̀rọ̀ rí.