12 Àwọn mààlúù yìí bá doríkọ ọ̀nà Beti Ṣemeṣi, wọ́n ń lọ tààrà láì yà sọ́tùn-ún tabi sósì. Wọ́n ń ké bí wọ́n ti ń lọ. Àwọn ọba Filistini maraarun tẹ̀lé wọn títí dé odi Beti Ṣemeṣi.
13 Àwọn ará ìlú Beti ṣemeṣi ń kórè ọkà lọ́wọ́ ní àfonífojì náà, bí wọ́n ti gbójú sókè, wọ́n rí àpótí ẹ̀rí. Inú wọn dùn pupọ pupọ bí wọ́n ti rí i.
14 Nígbà tí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà dé ibi oko Joṣua, ará Beti Ṣemeṣi, ó dúró níbẹ̀. Àpáta ńlá kan wà níbẹ̀, àwọn eniyan náà bá gé igi tí wọ́n fi kan kẹ̀kẹ́ ẹrù náà sí wẹ́wẹ́, wọ́n pa mààlúù mejeeji, wọ́n sì fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA.
15 Àwọn ọmọ Lefi bá gbé àpótí OLUWA náà, ati àpótí tí àwọn ohun tí wọ́n fi wúrà ṣe wà, wọ́n gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Lẹ́yìn náà, àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi rú ẹbọ sísun, ati oríṣìíríṣìí ẹbọ mìíràn sí OLUWA ní ọjọ́ náà.
16 Àwọn ọba Filistini ń wò wọ́n bí wọ́n ti ń ṣe, lẹ́yìn náà, wọ́n yipada sí ìlú Ekironi ní ọjọ́ náà gan-an.
17 Àwọn ará Filistia fi kókó ọlọ́yún marun-un náà tí wọ́n fi wúrà ṣe ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù. Ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ìlú kọ̀ọ̀kan; Aṣidodu, Gasa, Aṣikeloni, Gati ati Ekironi.
18 Wọ́n sì fi àwọn èkúté marun-un tí wọ́n fi wúrà ṣe ranṣẹ. Èkúté kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ìlú àwọn ọba Filistini maraarun. Àwọn maraarun wà fún àwọn ìlú olódi àwọn ọba Filistini, pẹlu àwọn ìletò kéékèèké wọn, tí kò ní odi. Àpáta ńlá tí ó wà ninu oko Joṣua ará Beti Ṣemeṣi, tí àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí OLUWA náà lé wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ títí di òní olónìí.