11 Àwọn yìí ṣe onínú rere ju àwọn Juu ti Tẹsalonika lọ. Wọ́n fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Lojoojumọ ni wọ́n ń wá inú Ìwé Mímọ́ wò láti rí bí àwọn ohun tí wọ́n kọ́ wọn rí bẹ́ẹ̀.
12 Pupọ ninu wọn gbàgbọ́, ati pupọ ninu àwọn Giriki tí wọ́n jẹ́ eniyan pataki-pataki, lọkunrin ati lobinrin.
13 Ṣugbọn nígbà tí àwọn Juu ní Tẹsalonika mọ̀ pé Paulu ti tún waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní Beria, wọ́n wá sibẹ láti ṣe màdàrú ati láti dá rúkèrúdò sílẹ̀.
14 Lẹsẹkẹsẹ ni àwọn onigbagbọ bá ṣe ètò fún Paulu láti lọ sí èbúté. Ṣugbọn Sila ati Timoti dúró ní Beria.
15 Àwọn tí ó sin Paulu lọ mú un dé Atẹni. Wọ́n wá gba ìwé pada fún Sila ati Timoti pé kí wọ́n tètè wá bá a.
16 Nígbà tí Paulu ń dúró dè wọ́n ní Atẹni, ó rí ìlú náà bí ó ti kún fún ère oriṣa. Eléyìí sì dùn ún dọ́kàn.
17 Nítorí náà, ó ń bá àwọn Juu ati àwọn olùfọkànsìn tí kì í ṣe Juu jiyàn ninu ilé ìpàdé ní ojoojumọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ń ṣe láàrin ọjà, ó ń bá ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nítòsí sọ̀rọ̀.