13 Ṣugbọn nígbà tí àwọn Juu ní Tẹsalonika mọ̀ pé Paulu ti tún waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní Beria, wọ́n wá sibẹ láti ṣe màdàrú ati láti dá rúkèrúdò sílẹ̀.
14 Lẹsẹkẹsẹ ni àwọn onigbagbọ bá ṣe ètò fún Paulu láti lọ sí èbúté. Ṣugbọn Sila ati Timoti dúró ní Beria.
15 Àwọn tí ó sin Paulu lọ mú un dé Atẹni. Wọ́n wá gba ìwé pada fún Sila ati Timoti pé kí wọ́n tètè wá bá a.
16 Nígbà tí Paulu ń dúró dè wọ́n ní Atẹni, ó rí ìlú náà bí ó ti kún fún ère oriṣa. Eléyìí sì dùn ún dọ́kàn.
17 Nítorí náà, ó ń bá àwọn Juu ati àwọn olùfọkànsìn tí kì í ṣe Juu jiyàn ninu ilé ìpàdé ní ojoojumọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ń ṣe láàrin ọjà, ó ń bá ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nítòsí sọ̀rọ̀.
18 Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan ninu àwọn ọmọlẹ́yìn Epikurusi ati àwọn Sitoiki bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Kí ni aláhesọ yìí ń wí?”Àwọn mìíràn ní, “Ó jọ pé òjíṣẹ́ oriṣa àjèjì kan ni!” Nítorí ó ń waasu nípa Jesu ati ajinde.
19 Ni wọ́n bá ní kí ó kálọ sí Òkè Areopagu. Wọ́n wá bi í pé, “Ǹjẹ́ a lè mọ ohun tí ẹ̀kọ́ titun tí ò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́?