16 Ni ó bá lé wọn kúrò ní kóòtù.
17 Ni gbogbo wọ́n bá mú Sositene, olórí ilé ìpàdé àwọn Juu, wọ́n ń lù ú níwájú kóòtù. Ṣugbọn Galio kò pé òun rí wọn.
18 Paulu tún dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i. Lẹ́yìn náà ó dágbére fún àwọn onigbagbọ, ó bá wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria; Pirisila ati Akuila bá a lọ. Paulu gé irun rẹ̀ ní ìlú Kẹnkiria nítorí pé ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan.
19 Nígbà tí wọ́n dé Efesu, Paulu fi Pirisila ati Akuila sílẹ̀, ó lọ sinu ilé ìpàdé àwọn Juu, ó lọ bá àwọn Juu sọ̀rọ̀.
20 Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn fún àkókò díẹ̀ sí i, ṣugbọn kò gbà.
21 Bí ó ti fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó ní, “N óo tún pada wá sí ọ̀dọ̀ yín bí Ọlọrun bá fẹ́.” Ó bá kúrò ní Efesu.
22 Nígbà tí ó gúnlẹ̀ ní Kesaria, ó lọ kí ìjọ ní Jerusalẹmu. Lẹ́yìn náà ó lọ sí Antioku.