6 Àwọn angẹli meje tí wọ́n mú kàkàkí meje lọ́wọ́ bá múra láti fun kàkàkí wọn.
7 Ekinni fun kàkàkí rẹ̀. Ni yìnyín ati iná pẹlu ẹ̀jẹ̀ bá tú dà sórí ilẹ̀ ayé. Ìdámẹ́ta ayé bá jóná, ati ìdámẹ́ta àwọn igi ati gbogbo koríko tútù.
8 Angẹli keji fun kàkàkí rẹ̀. Ni a bá ju nǹkankan tí ó dàbí òkè gíga tí ó ń jóná sinu òkun. Ó bá sọ ìdámẹ́ta òkun di ẹ̀jẹ̀.
9 Ìdámẹ́ta gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tí ó wà ninu òkun ni wọ́n kú. Ìdámẹ́ta àwọn ọkọ̀ ojú òkun ni wọ́n sì fọ́ túútúú.
10 Angẹli kẹta fun kàkàkí rẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá kan bá já bọ́ láti ọ̀run. Ó bẹ̀rẹ̀ sí jóná bí ògùṣọ̀. Ó bá já sinu ìdámẹ́ta àwọn odò ati ìsun omi.
11 Orúkọ ìràwọ̀ náà ni “Igi-kíkorò.” Ó mú kí ìdámẹ́ta omi korò, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó sì kú nítorí oró tí ó wà ninu omi.
12 Angẹli kẹrin fun kàkàkí rẹ̀, ìdámẹ́ta oòrùn kò bá lè ràn mọ́; ati ìdámẹ́ta òṣùpá, ati ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀. Ìdámẹ́ta wọn ṣókùnkùn, kò bá sí ìmọ́lẹ̀ fún ìdámẹ́ta ọ̀sán ati ìdámẹ́ta òru.