Kọrinti Keji 5:10-16 BM

10 Nítorí gbogbo wa níláti lọ siwaju Kristi bí a ti rí, láti lọ jẹ́ ẹjọ́. Níbẹ̀ ni olukuluku yóo ti gba ohun tí ó tọ́ sí i fún oríṣìíríṣìí ìwà tí ó ti hù nígbà tí ó wà ninu ara, ìbáà ṣe rere, ìbáà ṣe burúkú.

11 Nítorí náà nígbà tí àwa ti mọ ohun tí ìbẹ̀rù Oluwa jẹ́, a mọ̀ pé eniyan ni a lè gbìyànjú láti yí lọ́kàn pada. Ọlọrun mọ irú ẹni tí a jẹ́, mo sì rò pé ẹ̀rí-ọkàn yín jẹ́rìí sí mi pẹlu.

12 Kò tún nílò pé kí á máa pọ́n ara wa fun yín mọ́. Ṣugbọn èyí yóo jẹ́ anfaani fun yín láti máa fi wá ṣògo, kí ẹ lè máa rí ohun wí fún àwọn tí wọn ń ṣògo nípa nǹkan ti òde ara, tí kì í ṣe nípa nǹkan ti inú ọkàn.

13 Bí ó bá dàbí ẹni pé orí wa kò pé, nítorí ti Ọlọrun ni. Bí a bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n, a jẹ́ ẹ fun yín,

14 nítorí ìfẹ́ Kristi ni ó ń darí wa, nígbà tí a ti mọ̀ pé ẹnìkan ti kú fún gbogbo eniyan, a mọ̀ pé ikú gbogbo eniyan ni ó gbà kú.

15 Ìdí tí Kristi fi kú fún gbogbo eniyan ni pé kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe wà láàyè fún ara wọn, ṣugbọn kí wọ́n lè wà láàyè fún ẹni tí ó kú fún wa, tí Ọlọrun sì jí dìde.

16 Àyọrísí gbogbo èyí ni pé, láti ìgbà yìí lọ, àwa kò tún ní wo ẹnikẹ́ni ní ìwò ti ẹ̀dá mọ́. Nígbà kan ìwò ti ẹ̀dá ni à ń wo Kristi, ṣugbọn a kò tún wò ó bẹ́ẹ̀ mọ́.