2 Lẹ́yìn tí ó ti gbà láti fún àwọn òṣìṣẹ́ náà ní owó fadaka kan fún iṣẹ́ ojúmọ́, ó ní kí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ ninu ọgbà àjàrà òun.
3 Ó tún jáde lọ ní agogo mẹsan-an òwúrọ̀, ó rí àwọn mìíràn tí wọn dúró ní ọjà láìṣe nǹkankan.
4 Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ lọ sinu ọgbà àjàrà mi, n óo sì fun yín ní ohun tí ó bá tọ́.’
5 Wọ́n bá lọ. Ọkunrin náà tún jáde lọ ní agogo mejila ọ̀sán ati ní agogo mẹta ọ̀sán, ó tún ṣe bákan náà.
6 Nígbà tí ó jáde ní agogo marun-un ìrọ̀lẹ́, ó rí àwọn mìíràn tí wọn dúró, ó bi wọ́n pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi dúró láti àárọ̀ láìṣe nǹkankan?’
7 Wọ́n dá a lóhùn pé, ‘Nítorí ẹnikẹ́ni kò gbà wá síṣẹ́ ni.’ Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ lọ sinu ọgbà àjàrà mi.’
8 “Nígbà tí ọjọ́ rọ̀, ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́, kí o fún wọn ní owó wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó dé gbẹ̀yìn, títí dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó kọ́kọ́ dé.’