3 “Oluwa, wọ́n ti pa àwọn wolii rẹ, wọ́n ti wó pẹpẹ ìrúbọ rẹ, èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá mi láti pa.”
4 Ṣugbọn kí ni Ọlọrun wí fún un? Ó ní “Ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan ṣì kù fún mi tí wọn kò tíì wólẹ̀ bọ Baali rí.”
5 Bẹ́ẹ̀ náà ló rí ní àkókò yìí, àwọn kan kù tí Ọlọrun yàn nítorí oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀.
6 Tí ó bá wá jẹ́ pé nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni Ọlọrun fi yàn wọ́n, kò tún lè jẹ́ nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, oore-ọ̀fẹ́ kò ní jẹ́ oore-ọ̀fẹ́ mọ́.
7 Kí wá ni? Ohun tí Israẹli ń wá kò tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Ṣugbọn ó tẹ àwọn díẹ̀ tí a yàn ninu wọn lọ́wọ́. Etí àwọn yòókù di sí ìpè Ọlọrun,
8 gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Ọlọrun fún wọn ní iyè tí ó ra,ojú tí kò ríran,ati etí tí kò gbọ́ràn títí di òní olónìí.”
9 Dafidi náà sọ pé,“Jẹ́ kí àsè wọn di tàkúté ati àwọ̀n,kí ó gbé wọn ṣubú,kí ó mú ẹ̀san bá wọn.