2 Bi nwọn ti pè wọn, bẹ̃ni nwọn lọ kuro lọdọ wọn: nwọn rubọ si Baalimu, nwọn si fi turari joná si ere fifin.
3 Mo kọ́ Efraimu pẹlu lati rìn, mo dì wọn mu li apa, ṣugbọn nwọn kò mọ̀ pe mo ti mu wọn lara dá.
4 Mo fi okùn enia fà wọn, ati idè ifẹ: mo si ri si wọn bi awọn ti o mu ajàga kuro li ẹrẹkẹ wọn, mo si gbe onjẹ kalẹ niwaju wọn.
5 On kì yio yipadà si ilẹ Egipti, ṣugbọn ara Assiria ni yio jẹ ọba rẹ̀, nitori nwọn kọ̀ lati yipadà.
6 Idà yio si ma gbe inu ilu rẹ̀, yio si run ìtikun rẹ̀, yio si jẹ wọn run, nitori ìmọran ara wọn.
7 Awọn enia mi si tẹ̀ si ifàsẹhin kuro lọdọ mi: bi o tilẹ̀ ṣepe nwọn pè wọn si Ọga-ogo jùlọ, nwọn kò jùmọ gbe e ga.
8 Emi o ha ṣe jọwọ rẹ lọwọ, Efraimu? emi o ha ṣe gbà ọ silẹ, Israeli? emi o ha ti ṣe ṣe ọ bi Adma? emi o ha ti ṣe gbe ọ kalẹ bi Seboimu, ọkàn mi yi ninu mi, iyọnu mi gbiná pọ̀.