33 Lati Jordani nihà ilà-õrùn, gbogbo ilẹ Gileadi, awọn enia Gadi, ati awọn enia Reubeni, ati awọn enia Manasse, lati Aroeri, ti o wà leti odò Arnoni, ani Gileadi ati Baṣani.
34 Ati iyokù iṣe Jehu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, ati gbogbo agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
35 Jehu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀: nwọn si sìn i ni Samaria. Jehoahasi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
36 Ọjọ ti Jehu jọba lori Israeli ni Samaria sì jẹ ọdun mejidilọgbọ̀n.