5 Ẹ jẹ ki awọn alufa ki o mu u tọ̀ ara wọn, olukuluku lati ọwọ ojulùmọ rẹ̀: ẹ si jẹ ki nwọn ki o tun ẹya ile na ṣe, nibikibi ti a ba ri ẹya.
6 O si ṣe, li ọdun kẹtalelogun Jehoaṣi ọba, awọn alufa kò iti tun ẹya ile na ṣe.
7 Nigbana ni Jehoaṣi ọba pè Jehoiada alufa, ati awọn alufa miràn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò tun ẹya ile na ṣe? njẹ nisisiyi ẹ máṣe gbà owo mọ lọwọ awọn ojulùmọ nyin, bikòṣepe ki ẹ fi i lelẹ fun ẹya ile na.
8 Awọn alufa si ṣe ilerí lati má gbà owo lọwọ awọn enia mọ, tabi lati má tun ẹya ile na ṣe.
9 Ṣugbọn Jehoiada alufa mu apoti kan, o si dá ideri rẹ̀ lu, o si fi i si ẹba pẹpẹ na, li apa ọtún bi ẹnikan ti nwọ̀ inu ile Oluwa lọ: awọn alufa ti o si ntọju iloro na fi gbogbo owo ti a mu wá inu ile Oluwa sinu rẹ̀.
10 O si ṣe, nigbati nwọn ri pe, owo pupọ̀ mbẹ ninu apoti na, ni akọwe ọba, ati olori alufa gòke wá, nwọn si dì i sinu apò, nwọn si kà iye owo ti a ri ninu ile Oluwa.
11 Nwọn si fi owo na ti a kà le ọwọ awọn ti o nṣiṣẹ na, awọn ti o nṣe abojuto ile Oluwa: nwọn si ná a fun awọn gbẹnagbẹna, ati awọn akọle, ti nṣiṣẹ ile Oluwa.