1 LI ọdun kẹtadilogun Peka ọmọ Remaliah, Ahasi ọmọ Jotamu ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.
2 Ẹni ogún ọdun ni Ahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu, kò si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀.
3 Ṣugbọn o rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, nitõtọ, o si mu ki ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná pẹlu, gẹgẹ bi iṣe irira awọn keferi, ti Oluwa le jade niwaju awọn ọmọ Israeli.
4 O si rubọ, o si sun turari ni ibi giga wọnni, ati lori awọn òke kekeke, ati labẹ gbogbo igi tutu.
5 Nigbana ni Resini ọba Siria ati Peka ọmọ Remaliah ọba Israeli gòke wá si Jerusalemu lati jagun: nwọn si do tì Ahasi, ṣugbọn nwọn kò le bori rẹ̀.
6 Li akokò na, Resini ọba Siria gbà Elati pada fun Siria, o si lé awọn enia Juda kuro ni Elati: awọn ara Siria si wá si Elati, nwọn si ngbe ibẹ titi di oni yi.