4 On mu ibi giga wọnni kuro, o si fọ́ awọn ere, o si wó awọn ere oriṣa lulẹ, o si fọ́ ejò idẹ na tútu ti Mose ti ṣe: nitori titi di ọjọ wọnni, awọn ọmọ Israeli nsun turari si i: a si pè e ni Nehuṣtani.
5 O gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun Israeli; ati lẹhin rẹ̀ kò si ẹniti o dabi rẹ̀ ninu gbogbo awọn ọba Juda, bẹ̃ni ṣãju rẹ̀ kò si ẹnikan.
6 Nitoriti o faramọ Oluwa, kò si lọ kuro lẹhin rẹ̀, ṣugbọn o pa ofin rẹ̀ wọnni mọ, ti Oluwa ti pa li aṣẹ fun Mose.
7 Oluwa si wà pẹlu rẹ̀; o si ṣe rere nibikibi ti o ba jade lọ: o si ṣọ̀tẹ si ọba Assiria, kò si sìn i mọ.
8 On kọlù awọn ara Filistia, ani titi de Gasa, ati agbègbe rẹ̀, lati ile iṣọ awọn olùṣọ titi de ilu olodi.
9 O si ṣe li ọdun kẹrin Hesekiah ọba, ti iṣe ọdun keje Hoṣea ọmọ Ela ọba Israeli, ni Ṣalmaneseri ọba Assiria gòke wá si Samaria, o si dotì i.
10 Lẹhin ọdun mẹta nwọn kó o; ani li ọdun kẹfa Hesekiah, eyini ni ọdun kẹsan Hoṣea ọba Israeli li a kó Samaria.