1 ẸNI ọdun mẹjọ ni Josiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun mọkanlelọgbọ̀n ni Jerusalemu, Orukọ iya rẹ̀ ni Jedida, ọmọbinrin Adaiah ti Boskati.
2 On si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa o si rìn li ọ̀na Dafidi baba rẹ̀ gbogbo, kò si yipada si apa ọ̀tún tabi si apa òsi.
3 O si ṣe li ọdun kejidilogun Josiah ọba li ọba rán Ṣafani ọmọ Asaliah ọmọ Mesullamu, akọwe, si ile Oluwa, wipe,
4 Gòke tọ̀ Hilkiah olori alufa lọ, ki o le ṣirò iye fadakà ti a mu wá sinu ile Oluwa, ti awọn olùtọju iloro ti kojọ lọwọ awọn enia:
5 Ẹ si jẹ ki wọn ki o fi le awọn olùṣe iṣẹ na lọwọ, ti nṣe alabojuto ile Oluwa: ki ẹ si jẹ ki wọn ki o fi fun awọn olùṣe iṣẹ na ti mbẹ ninu ile Oluwa, lati tun ibi ẹya ile na ṣe.