2 Oluwa si rán ẹgbẹ́ ogun awọn ara Kaldea si i, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Siria, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Moabu, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ọmọ Ammoni, o si rán wọn si Juda lati pa a run, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti sọ nipa awọn iranṣẹ rẹ̀ awọn woli.
3 Nitõtọ lati ẹnu Oluwa li eyi ti wá sori Juda, lati mu wọn kuro niwaju rẹ̀, nitori ẹ̀ṣẹ Manasse, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe;
4 Ati nitori ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ ti o ta silẹ pẹlu: nitoriti o fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kún Jerusalemu; ti Oluwa kò fẹ darijì.
5 Ati iyokù iṣe Jehoiakimu, ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
6 Bẹ̃ni Jehoiakimu sùn pẹlu awọn baba rẹ̀: Jehoiakini ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
7 Ọba Egipti kò si tun jade kuro ni ilẹ rẹ̀ mọ; nitori ọba Babeli ti gbà gbogbo eyiti iṣe ti ọba Egipti lati odò Egipti wá titi de odò Euferate.
8 Ẹni ọdun mejidilogun ni Jehoiakini nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li oṣù mẹta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Nehuṣta, ọmọbinrin Elnatani ti Jerusalemu.