18 Njẹ ọkunrin yi sá ti fi ere aiṣõtọ rà ilẹ kan; nigbati o si ṣubu li ògedengbé, o bẹ́ li agbedemeji, gbogbo ifun rẹ̀ si tú jade.
19 O si di mimọ̀ fun gbogbo awọn ti ngbe Jerusalemu; nitorina li a fi npè igbẹ́ na ni Akeldama li ède wọn, eyini ni, Igbẹ́ ẹ̀jẹ.
20 A sá kọ ọ ninu Iwe Psalmu pe, Jẹ ki ibujoko rẹ̀ ki o di ahoro, ki ẹnikan ki o má si ṣe gbé inu rẹ̀, ati oyè rẹ̀, ni ki ẹlomiran gbà.
21 Nitorina ninu awọn ọkunrin wọnyi ti nwọn ti mba wa rìn ni gbogbo akoko ti Jesu Oluwa nwọle, ti o si njade lãrin wa,
22 Bẹ̀rẹ lati igba baptismu Johanu wá, titi o fi di ọjọ na ti a gbé e lọ soke kuro lọdọ wa, o yẹ ki ọkan ninu awọn wọnyi ṣe ẹlẹri ajinde rẹ̀ pẹlu wa.
23 Nwọn si yàn awọn meji, Josefu ti a npè ni Barsabba, ẹniti a sọ apele rẹ̀ ni Justu, ati Mattia.
24 Nwọn si gbadura, nwọn si wipe, Iwọ, Oluwa, olumọ̀ ọkàn gbogbo enia, fihàn ninu awọn meji yi, ewo ni iwọ yàn,