15 Nwọn si nwipe, Ará, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe nkan wọnyi? Enia oniru ìwa kanna bi ẹnyin li awa pẹlu ti a nwasu ihinrere fun nyin, ki ẹnyin ki o yipada kuro ninu ohun asan wọnyi si Ọlọrun alãye, ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn:
16 Ẹni, ni awọn iran ti o ti kọja jọwọ gbogbo orilẹ-ède, lati mã rìn li ọna tiwọn.
17 Ṣugbọn ko fi ara rẹ̀ silẹ li ailẹri, ni ti o nṣe rere, o nfun nyin ni òjo lati ọrun wá, ati akokò eso, o nfi onjẹ ati ayọ̀ kún ọkàn nyin.
18 Diẹ li o kù ki nwọn ki o ma le fi ọ̀rọ wọnyi da awọn enia duro, ki nwọn ki o máṣe rubọ bọ wọn.
19 Awọn Ju kan si ti Antioku ati Ikonioni wá, nigbati nwọn yi awọn enia li ọkàn pada, nwọn si sọ Paulu li okuta, nwọn wọ́ ọ jade kuro ni ilu na, nwọn ṣebi o kú.
20 Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin duro tì i yiká, o dide, o si wọ̀ ilu na lọ: ni ijọ keji o ba Barnaba lọ si Derbe.
21 Nigbati nwọn si ti wasu ihinrere fun ilu na, ti nwọn si ni ọmọ-ẹ̀hin pupọ, nwọn pada lọ si Listra, ati Ikonioni, ati si Antioku.