5 Ṣugbọn awọn wọnyi ti lọ ṣiwaju, nwọn nduro dè wa ni Troa.
6 Awa si ṣikọ̀ lati Filippi wá lẹhin ọjọ aiwukara, a si de ọdọ wọn ni Troasi ni ijọ karun; nibiti awa gbé duro ni ijọ meje.
7 Ati ni ọjọ ikini ọ̀sẹ nigbati awọn ọmọ-ẹhin pejọ lati bù akara, Paulu si wasu fun wọn, o mura ati lọ ni ijọ keji: o si fà ọ̀rọ rẹ̀ gùn titi di arin ọganjọ.
8 Fitilà pipọ si wà ni yàrá oke na, nibiti a gbé pejọ si.
9 Ọdọmọkunrin kan ti a npè ni Eutiku si joko li oju ferese, orun si wọ̀ ọ lara: bi Paulu si ti pẹ ni iwasu, o ta gbọ́ngbọ́n loju orun, o ṣubu lati oke kẹta wá silẹ, a si gbé e dide li okú.
10 Nigbati Paulu si sọkalẹ, o wolẹ bò o, o gbá a mọra, o ni, Ẹ má yọ ara nyin lẹnu; nitori ẹmí rẹ̀ mbẹ ninu rẹ̀.
11 Nigbati o si tún gòke lọ, ti o si bù akara, ti o si jẹ, ti o si sọ̀rọ pẹ titi o fi di afẹmọjumọ́, bẹ̃li o lọ.