13 Nigbati nwọn si kiyesi igboiya Peteru on Johanu, ti nwọn si mọ̀ pe, alaikẹkọ ati òpe enia ni nwọn, ẹnu yà wọn; nwọn si woye wọn pe, nwọn a ti ma ba Jesu gbé.
14 Nigbati nwọn si nwò ọkunrin na ti a mu larada, ti o ba wọn duro, nwọn kò ri nkan wi si i.
15 Ṣugbọn nigbati nwọn si paṣẹ pe ki nwọn jade kuro ni igbimọ, nwọn ba ara wọn gbèro,
16 Wipe, Kili a o ti ṣe awọn ọkunrin wọnyi? ti pe iṣẹ àmi ti o daju ti ọwọ́ wọn ṣe, o hàn gbangba fun gbogbo awọn ti ngbé Jerusalemu; awa kò si le sẹ́ ẹ.
17 Ṣugbọn ki o má bà tàn kalẹ siwaju mọ́ lãrin awọn enia, ẹ jẹ ki a kìlọ fun wọn pe, lati isisiyi lọ ki nwọn ki o máṣe fi orukọ yi sọ̀rọ fun ẹnikẹni mọ́.
18 Nigbati nwọn si pè wọn, nwọn paṣẹ fun wọn, ki nwọn máṣe sọ̀rọ rara, bẹni ki nwọn máṣe kọ́ni li orukọ Jesu mọ́.
19 Ṣugbọn Peteru on Johanu dahùn, nwọn si wi fun wọn pe, Bi o ba tọ́ li oju Ọlọrun lati gbọ́ ti nyin jù ti Ọlọrun lọ, ẹ gbà a rò,