14 A si nyàn awọn ti o gbà Oluwa gbọ kun wọn si i, ati ọkunrin ati obinrin;
15 Tobẹ̃ ti nwọn ngbé awọn abirùn jade si igboro, ti nwọn ntẹ́ wọn si ori akete ati ohun ibĩrọgbọku, pe bi Peteru ba nkọja ki ojiji rẹ̀ tilẹ le ṣijibò omiran ninu wọn.
16 Ọ̀pọ enia si ko ara wọn jọ lati awọn ilu ti o yi Jerusalemu ka, nwọn nmu awọn abirùn wá, ati awọn ti ara kan fun ẹmi aimọ́: a si ṣe dida ara olukuluku wọn.
17 Ṣugbọn olori alufa dide, ti on ti gbogbo awọn ti nwọn wà lọdọ rẹ̀ (ti iṣe ẹya ti awọn Sadusi), nwọn si kún fun owu.
18 Nwọn si nawọ́ mu awọn aposteli, nwọn si fi wọn sinu tubu.
19 Ṣugbọn angẹli Oluwa ṣí ilẹkun tubu li oru; nigbati o si mu wọn jade, o wipe,
20 Ẹ lọ, ẹ duro, ki ẹ si mã sọ gbogbo ọ̀rọ iye yi fun awọn enia ni tẹmpili.