31 On li Ọlọrun fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ gbéga lati jẹ Ọmọ alade ati Olugbala, lati fi ironupiwada fun Israeli, ati idariji ẹ̀ṣẹ.
32 Awa si li ẹlẹri nkan wọnyi; ati Ẹmí Mimọ́ pẹlu, ti Ọlọrun fifun awọn ti o gbọ́ tirẹ̀.
33 Ṣugbọn nigbati nwọn gbọ́ eyi, àiya wọn gbà ọgbẹ́ de inu, nwọn gbèro ati pa wọn.
34 Ṣugbọn ọkan ninu ajọ igbimọ, ti a npè ni Gamalieli, Farisi ati amofin, ti o ni iyìn gidigidi lọdọ gbogbo enia, o dide duro, o ni ki a mu awọn aposteli bì sẹhin diẹ;
35 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ọkunrin Israeli, ẹ kiyesi ara nyin li ohun ti ẹnyin npete ati ṣe si awọn ọkunrin wọnyi.
36 Nitori ṣaju ọjọ wọnyi ni Teuda dide, o nwipe ẹni nla kan li on; ẹniti ìwọn irinwo ọkunrin gbatì: ẹniti a pa; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a tú wọn ká, a si sọ wọn di asan.
37 Lẹhin ọkunrin yi ni Juda ti Galili dide lakoko kikà enia, o si fà enia pipọ lẹhin rẹ̀: on pẹlu ṣegbé; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a fọn wọn ká.