6 Dáfídì ti wí pé Ẹnikẹ́ni tí ó bá darí àti kọlu àwọn ará Jébúsì ni yóò di olórí balógun, Jóábù ọmọ Sérúíà lọ sókè lákòókọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó sì gba olórí.
7 Dáfídì sì mú lọ sókè ibùgbé nínú odi alágbára, bẹ́ẹ̀ ní a sì ń pè é ni ìlú Dáfídì.
8 Ó sì kọ́ àwọn ìlú náà yíkákiri Rẹ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn alátìlẹ́yìn ibi ìtẹ́jú ilẹ̀ si àyíká ògiri. Nígbà tí Jóábù sì pa ìyókù àwọn ìlú náà run.
9 Nígbà náà Dáfídì sì jẹ́ alágbára kún alágbára nítorí pé Olúwa àwọn ọmọ ogun wà pẹ̀lú Rẹ̀.
10 Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè alágbára ọkùnrin Dáfídì, àwọn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì fún ìjọba Rẹ̀ ní àtìlẹ́yìn tó lágbára láti mú un tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sèlérí:
11 èyí sì ni iye àwọn alágbára ọkùnrin Dáfídì:Jásóbéámù ọmọ Hákúmónì, òun sì ni olórí nínú àwọn ìjòyè, ó sì gbé ọ̀kọ̀ Rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa ní ogun ẹ̀ẹ̀kan.
12 Lẹ́yìn Rẹ̀ sì ni Élíásárì ọmọ Dódáì àwọn ará Áhóhì, ọ̀kan lára àwọn mẹ́ta ọkùnrin alágbára.