1 Kíróníkà 12:18-24 BMY

18 Nígbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ wa sórí Ámásáyà ìjòyè àwọn ọgbọ̀n, ó sì wí pé:“Tìrẹ ni àwa ń se, ìwọ Dáfídì!Àwa pẹ̀lú rẹ, ìwọ ọmọ Jésè!Àlàáfíà, àlàáfíà fún o,àti àlàáfíà fún àwọn tí ó ràn ó lọ́wọ́,nítorí Ọlọ́run Rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.”Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì gbà wọ́n ó sì mú wọn jẹ olórí ẹgbẹ́ ogun.

19 Díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin Mánásè sì yà sí ọ̀dọ̀ Dáfídì nígbà tí ó lọ pẹ̀lú àwọn ará Fílístínì láti bá Ṣọ́ọ̀lù jà. (Òun àti àwọn ọkùnrin Rẹ̀ wọn kò sì ran ará Fílístínì lọ́wọ́ nítorí, lẹ́yìn àjùmọ̀sọ̀rọ̀, àwọn olórí wọn rán wọn jáde, wọ́n sì wí pé Yóò ná wa ní orí wa tí ó bá sì fi sílẹ̀ fún ọ̀gá Rẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù).

20 Nígbà tí Dáfídì lọ sí Ṣíkílágì, àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin ti Mánásè ẹnití ó sì yà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ádínà, Jósábádì, Jédíáélì, Míkáẹ́lì, Jósábádì, Élíhù àti Ṣílátì, àwọn olórí ìrẹ́pọ̀ ti ẹgbẹgbẹ̀rún ní Mánásè.

21 Wọ́n sì ran Dáfídì lọwọ lórí ẹgbẹ́ ogun náà, nítorí gbogbo wọn ni akọni ènìyàn àwọn sì tún ni olórí nínú àwọn ọmọogun Rẹ̀.

22 Ọjọ́ dé ọjọ́ ni àwọn ọkùnrin wá láti ran Dáfídì lọ́wọ́, títí tí ó fi ní àwọn ológun ńlá, bí ogun Ọlọ́run,

23 Àwọn wọ̀nyí sì ni iye ọkùnrin tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun àwọn ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì láti yí ìjọba Dáfídì padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ:

24 Ọkùnrin Júdà, gbé àṣà àti ọ̀kọ̀, ẹgbẹ̀ta lé lọ́gọ́rin (6,080) tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun;