1 Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti kọ́ ilé fún ara Rẹ̀ ní ìlú Dáfídì. Ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ó sì pàgọ́ fún un.
2 Nígbà náà Dáfídì wí pé, Kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Léfì ni ó lè gbé Àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí Olúwa yàn wọ́n láti gbé àpóti ẹ̀rí Olúwa àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú Rẹ̀ títí láé.
3 Dáfídì kó gbogbo àwon ọmọ Ísírélì jọ ní Jérúsálẹ́mù láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibi tí ó ti pèṣè sílẹ̀ fún un.
4 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Árónì àti àwọn ọmọ Léfì tí Dáfídì pèjọ papọ̀:
5 Ọgọ́fà nínú àwọn ọmọ Kóhátì;Úríélì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.