16 Dáfídì sọ fún àwọn olórí àwọn Léfì láti yan àwọn arákùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí akọrin láti kọ orin ayọ̀, pẹ̀lú àwọn ohun-èlò orin pisalitérì, dùùrù, àti Ṣíḿbálì.
17 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Léfì yan Hámánì ọmọ Jóẹ́lì; àti nínú àwọn arákùnrin Rẹ̀, Ásáfù ọmọ Bérékíà, àti nínú àwọn ọmọ Mérárì arákùnrin wọn, Étanì ọmọ Kúṣáíà;
18 àti pẹ̀lú wọn àwọn arákùnrin wọn tí a yàn bí olùrànlọ́wọ́ wọn: Ṣekaríyà, Jásíélì; Ṣémírámótì, Jéhíélì, Únì, Élíféléhù, Míkíméíà, àti àwọn asọ́bodè Obedi-Edomu àti Jélíélì.
19 Àwọn akọrin sì ni Hémánì, Ásáfù, àti Étanì ti àwọn ti kíḿbálì idẹ tí ń dún kíkan;
20 Ṣekaríyà, Ásíélì, Ṣémírámótì, Jẹ́híélì, Únínì, Élíábù, Máséíà àti Beniáyà àwọn tí ó gbọdọ̀ ta láétírì gẹ́gẹ́ bí àlámótì,
21 Àti Mátítíyà, Élíféléhù, Míkínéyà, Obedi-Édómù, Jélíélì àti Ásásíyà ni ó ní láti ta ohun èlò olóhùn goro, láti darí gẹ́gẹ́ bí Ṣémínítì.
22 Kénáníyá orin àwọn ará Léfì ni ó wà ní ìkáwọ́ orin èyí sì ni ojúṣe nítorí ó mòye nípa Rẹ̀.