26 Nítori Ọlọ́run tì ràn wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Léfì énì tí ó gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa, akọ màlúù méje pẹ̀lú àgbò méje láti fi sé ìrúbọ.
27 Nísinsìn yìí Dáfídì sì wọ aṣọ ìgúnwà ọ̀gbọ̀ dáradára, gẹ́gẹ́ bí akọrin, àti Kenaníyà, ẹnití ó wà ní ìkáwó orin kíkọ àwọn akọrin. Dáfídì sì wọ aṣọ ìgúnwà fun fun.
28 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Ísírẹ́lì gbé àpótí ẹ̀rí àti májẹ̀mú Olúwa gòkè wá pẹ̀lú ariwo, pèlú àyíká ìhó ayọ̀ àti láti fọn fèrè ti ìpè, àti kíḿbálì, àti láti ta písálítérì; àti dùùrù olóhun goro.
29 Bí àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa ti ń wọ ìlú ńlá Dáfídì, Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù ń wò láti ojú fèrèsé nígbà tí ó sì rí ọba Dáfídì ń jó, ó sì ń ṣe àjọyọ̀, ó sì kẹ́gàn Rẹ̀ ní ọkàn Rẹ̀.