1 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dáfídì ti pàṣẹ fún un, wọ́n sì gbé ọrẹ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run.
2 Lẹ́yìn ọrẹ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ Olúwa.
3 Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Ísírẹ́lí ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èṣo àjàrà kan.
4 Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Léfì láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa, Ọlọ́run Ísírélì.
5 Ásáfù jẹ́ olóyè Ṣémírámótì, Jéhíelì, Mátítíyà, Élíábìlì, Bénáyà, Obedi-Édómù àti Jélíélì, Àwọn ni yóò lu lẹ́rì àti dùùrù háàpù. Ásáfù ni yóò lu símíbálì kíkan.
6 Àti Bénáià àti Jahaṣíélì àwọn àlùfáà ni yóò fọn ipè dédé níwájú àpótí ẹ̀rí méjẹ̀mú ti Ọlọ́run.