6 Dáfídì sì pín àwọn ọmọ Léfì sí ẹgbẹgbẹ́ láàrin àwọn ọmọ Léfì Gérísónì, Kóhátì àti Mérárì.
7 Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gérísónì:Ládánì àti Ṣíméhì.
8 Àwọn ọmọ LádánìJéhíélì ẹni àkọ́kọ́, Ṣétanì àti Jóẹ́lì ẹ̀kẹ́ta ní gbogbo wọn.
9 Àwọn ọmọ Ṣímè:Ṣélómótì, Hásíélì àti Háránì mẹ́ta ní gbogbo wọn.Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Ládánì.
10 Àti ọmọ Ṣímélì:Jáhátì, Ṣísà, Jéúsì àti Béríà.Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣíméhì mẹ́rin ni gbogbo wọn.
11 Jáhátì sì ni alákọ́kọ́ Ṣísà sì ni ẹlẹ́kejì, ṣùgbọ́n Jéúsì àti Béríà kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan.
12 Àwọn ọmọ kóhátì:Ámírámù, Ísárì, Hébúrónì àti Usíélì mẹ́rin ni gbogbo wọn.